Ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ń fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kì í ṣe ọ̀daràn sẹ́wọ̀n. Kí nìdí? Torí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, wọ́n sì ti kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe é. Ìjọba ilẹ̀ Korea ò sì fọwọ́ sí i pé ẹnì kan lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò jẹ́ kóun ṣiṣẹ́ ológun, torí náà, wọ́n ń rán àwọn Ẹlẹ́rìí tó bá kọ̀ lọ sẹ́wọ̀n. Kódà, láti ọgọ́ta (60) ọdún sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún (17,000) ni ìjọba ti fi sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

Kí wọ́n lè fún ọ̀rọ̀ yìí láfiyèsí, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè South Korea ṣe ìwé pẹlẹbẹ kan, àkòrí rẹ̀ ni  Conscientious Objection to Military Service in Korea. Ìwé pẹlẹbẹ náà sọ̀rọ̀ nípa bí ilẹ̀ Korea ṣe kọ̀ láti tẹ̀ lé òfin tí ìjọba àpapọ̀ fi lọ́lẹ̀ kárí ayé, tí wọn ò sì fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ó tún ṣàlàyé ṣókí nípa àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣẹ̀wọ̀n torí pé wọn ò fẹ́ ṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn. Ọ̀gbẹ́ni Dae-il Hong tó jẹ́ aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Korea àti Ọ̀gbẹ́ni Philip Brumley tó jẹ́ Agbẹjọ́rò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú New York ṣàlàyé síwájú sí i lórí ọ̀rọ̀ ìwà ìrẹ́jẹ tó ti ń ṣẹlẹ̀ látọdún yìí wá..

Kí làwọn èèyàn kárí ayé ti sọ nípa ìwà ìrẹ́jẹ tí orílẹ̀-èdè South Korea ń hù láìfi bò yìí?

Ọ̀gbẹ́ni Philip Brumley: Àwọn orílẹ̀-èdè kan ti sọ pé àwọn ò fara mọ́ bí ìjọba ilẹ̀ Korea ò ṣe fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe ẹ́. Nínú ìpàdé kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí kí wọ́n lè ṣàyẹ̀wò báwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń ṣe sí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, orílẹ̀-èdè mẹ́jọ, ìyẹn Hungary, France, Jámánì, Poland, Slovakia, Sípéènì, Amẹ́ríkà àti Ọsirélíà, ló rọ ìjọba ilẹ̀ Korea kí wọ́n ṣíwọ́ àti máa fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, kí wọ́n sì ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun fún wọn. *

Ọ̀gbẹ́ni Dae-il Hong: Nígbà tí wọ́n ń dá ẹjọ́ mẹ́rin tó kan àpapọ̀ àwọn ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ọ̀kan (501) tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè (ìyẹn Ìgbìmọ̀ CCPR) sọ pé ìjọba Orílẹ̀-èdè Korea ti fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n bó ṣe sọ pé wọ́n jẹ̀bi tó sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Ìgbìmọ̀ náà sọ pé “ẹ̀tọ́ láti kọṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ẹni ò gbà á láyè wà nínú òmìnira láti ní èrò tó wuni, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá fẹ́ àti ẹ̀sìn tó wuni. Ó gba ẹnikẹ́ni láyè láti kọ iṣẹ́ ológun tó bá ta ko ẹ̀sìn ẹni náà tàbí ohun tó gbà gbọ́. Wọn ò gbọ́dọ̀ fipá mú ẹnikẹ́ni ṣe ohun tó ta ko ẹ̀tọ́ rẹ̀.” *

Àjọ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, tàwọn náà ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè tún pe àfíyèsí sọ́rọ̀ yìí nínú ìròyìn kan tí wọ́n gbé jáde, wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní “Àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ẹ̀tọ́ láti kọṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ẹni ò gbà á láyè.” Ìròyìn yìí ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ohun tí ìjọba àpapọ̀ sọ kárí ayé, ìyẹn bí wọ́n ṣe fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun, tí wọ́n sì sọ pe ìjọba ò gbọ́dọ̀ máa pe àwọn yìí lẹ́jọ́ tàbí kí wọ́n máa fìyà jẹ wọ́n léraléra kí wọ́n lè fipá mú wọn ṣiṣẹ́ ológun. *

Kí ni ìjọba ilẹ̀ Korea ti wá ṣe nípa ohun táwọn èèyàn ń sọ kárí ayé?

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ

Ọ̀gbẹ́ni Philip Brumley: Ìjọba ilẹ̀ Korea ò tíì ṣe ohun tí Ìgbìmọ̀ CCPR ní kí wọ́n ṣe. Torí náà, wọ́n ti yẹ àdéhùn tí àwọn àtàwọn orílẹ̀-èdè míì kárí ayé tọwọ́ bọ̀, wọn ò sì gbà pé àwọn tó kọṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà á lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè South Korea àti Ilé Ẹjọ́ Ìjọba tún fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn èèyàn yìí pè, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n fọwọ́ rọ́ àṣe tí Ìgbìmọ̀ CCPR pa sẹ́yìn. Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Korea ò tíì ṣètò ohunkóhun tí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lè ṣe dípò, wọn ò sì ṣe ohunkóhun tí kò ní jẹ́ kí òfin máa fìyà jẹ àwọn èèyàn yìí.

Ipa wo ni ẹ̀wọ̀n tí wọ́n rán àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí lọ ní lórí wọn?

Ọ̀gbẹ́ni Dae-il Hong: Àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí kì í ṣojo. Tí ìjọba bá pè wọ́n lẹ́jọ́, wọ́n mọ̀ pé wọ́n á dá àwọn lẹ́bi, wọ́n á sì rán àwọn lọ sẹ́wọ̀n, síbẹ̀ wọ́n máa ń jẹ́ ìpè ìjọba. Wọn kì í fara pa mọ́. Àpẹẹrẹ rere ni wọ́n jẹ́ láwùjọ kí wọ́n tó lọ sẹ́wọ̀n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò ba ìwà wọn jẹ́ lẹ́wọ̀n. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé orúkọ wọn ti wà lákọọ́lẹ̀ pé ọ̀daràn ni wọ́n, ìyẹn kì í sì í jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti ríṣẹ́ ìjọba tí wọ́n bá jáde lẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n gbà wọ́n síṣẹ́ láwọn iléeṣẹ́ ńlá. Ọdún kan ààbọ̀ ni wọ́n fi wà lẹ́wọ̀n, àsìkò tó yẹ kí wọ́n fi gbé nǹkan gidi ṣe láyé wọn. Àfi káwọn mọ̀lẹ́bí wọn máa bá ìgbésí ayé lọ nígbà táwọn fi wà lẹ́wọ̀n. Irú ìyà yìí ò tọ́ sí wọn.

Ṣé ó yẹ kí ìjọba fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Korea, kí wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun?

Ọ̀gbẹ́ni Dae-il Hong: Bẹ́ẹ̀ kọ́ o! Ọ̀daràn kọ́ làwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí. Èèyàn àlàáfíà tó ń bọ̀wọ̀ fún òfin, tó ṣe tán láti sin ìlú ni wọ́n mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ní Korea àti kárí ayé. Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba, wọn kì í rú òfin, wọ́n máa ń san owó orí, wọ́n sì máa ń kọ́wọ́ ti ètò tí ìjọba bá ṣe fún àǹfààní ará ìlú. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, adájọ́ ilé ẹjọ́ kan nílẹ̀ Korea rán ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lọ sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun. Adájọ́ náà kọ́kọ́ sọ pé kò sóhun tí ilé ẹjọ́ lè ṣe ju kí wọ́n dá ọ̀dọ́kùnrin yìí lẹ́bi, ó wá ka ìdájọ́ náà. Ni adájọ́ náà bá dédé fi ìwé ọwọ́ rẹ̀ bojú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Ó ní láti jẹ́ pé ohun tó pa á lẹ́kún ni pé ó ká a lára pé wọ́n yan ọmọkùnrin náà jẹ bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn án. Àwọn míì tó wà níbẹ̀ náà rí i pé wọ́n yàn án jẹ lóòótọ́, wọ́n sì bú sẹ́kún.

Ọ̀gbẹ́ni Philip Brumley: Ká sòótọ́, ìsinsìnyí ló yẹ kí ìjọba ilẹ̀ Korea wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ tó ti wà nílẹ̀ tipẹ́ yìí, kí wọ́n sì gbé ètò kan kalẹ̀ tí kò ní jẹ́ kí ìyà máa jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

^ ìpínrọ̀ 5 Ìròyìn Àjọ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, ìyẹn “Report of the Working Group on the Universal Periodic Review,” 12 December 2012, A/HRC/22/10, ojú ìwé 7 àti 22, ìpínrọ̀ 44 àti 124.53.

^ ìpínrọ̀ 6 Jong-nam Kim et al. v. The Republic of Korea, communication no. 1786/2008, Àwọn Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ náà ṣe ní 25 October 2012, ojú ìwé 7, ìpínrọ̀ 7.4

^ ìpínrọ̀ 7 Ìròyìn Àjọ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, ìyẹn “Analytical report on conscientious objection to military service,” 3 June 2013, A/HRC/23/22, ojú ìwé 3 sí 8, ìpínrọ̀ 6 sí 24; ojú ìwé 9, 10, ìpínrọ̀ 32, 33.