Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JANUARY 25, 2017
SOUTH KOREA

“Ìpinnu Tó Dáa Jù tí Ilé Ẹjọ́ Ṣe Lọ́dún Yìí”

“Ìpinnu Tó Dáa Jù tí Ilé Ẹjọ́ Ṣe Lọ́dún Yìí”

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá ọ̀dọ́kùnrin mẹ́ta láre, orúkọ wọn ni Hye-min Kim, Lak-hoon Cho àti Hyeong-geun Kim. Inú wọn dùn pé ilé ẹjọ́ ò rán wọn lọ sẹ́wọ̀n. Ìyàlẹ́nu gbáà lèyí sì jẹ́ torí ohun tó gbé wọn délé ẹjọ́ ni pé wọ́n kọ̀ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe é, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọkùnrin ló sì ń ṣẹ̀wọ̀n ní South Korea lọ́dọọdún lórí ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́ta yìí náà ti ń retí pé àwọn á fi ẹ̀wọ̀n gbára, torí kì í ṣòní kì í ṣàná tí irú ẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀. Àwọn bàbá wọn ti ṣẹ̀wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn tó sì lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún [19,000] ló ti ṣẹ̀wọ̀n ṣáájú wọn. Mánigbàgbé ni ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Gwangju dá fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí pé “wọn ò jẹ̀bi”, èyí sì máa nípa rere lórí ibi tí ọ̀rọ̀ tó ti wà nílẹ̀ tipẹ́ yìí máa já sí.

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Ṣe “Ìpinnu Tó Dáa Jù tí Ilé Ẹjọ́ Ṣe Lọ́dún Yìí”

Ó kéré tán, iléeṣẹ́ ìròyìn tó tó igba [200] ló gbé ìròyìn yìí, kì í ṣe ohun tó máa tìdí ẹjọ́ àkọ́kọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá yìí jáde nìkan ni wọ́n ń tẹnu mọ́, wọ́n tún ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹnu àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń kun ọ̀rọ̀ tó ti wà nílẹ̀ yìí. Ìwé ìròyìn kan pè é ní “ìpinnu tó dáa jù tí ilé ẹjọ́ ṣe lọ́dún yìí”, ìwé ìròyìn míì sì ka ẹjọ́ yìí sí ọ̀kan lára àwọn ìpinnu márùn-ún tó dáa jù tí ilé ẹjọ́ ṣe lọ́dún 2016 lórílẹ̀-èdè South Korea.

Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé ojú táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lórí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ àtàwọn adájọ́ fi ń wo ọ̀rọ̀ yìí ti ń yí pa dà. Nínú àwọn ẹjọ́ kan tí wọ́n gbọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn adájọ́ rí i pé ohun táwọn ọkùnrin yìí gbà gbọ́ dá wọn lójú, kò sì sẹ́ni tó lè yí i pa dà. Wọ́n wá rí i pé táwọn bá fipá fa àwọn ọkùnrin yìí wọṣẹ́ ológun tàbí tí wọ́n fìyà jẹ wọ́n torí wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun, ṣe làwọn ń fi òmìnira ẹ̀rí ọkàn wọn dù wọ́n. Ibi táwọn adájọ́ yìí parí èrò sí ni pé àwọn ọkùnrin náà ní “ẹ̀tọ́ tó bófin mu” láti kọ̀ pé àwọn ò wọṣẹ́ ológun. Dípò kí àwọn adájọ́ ka àwọn ọkùnrin yìí sí àwọn tó ń sá fún iṣẹ́ ológun, ṣe ni wọ́n dá wọn láre nínú ẹjọ́ mẹ́rìndínlógún [16] tí wọ́n gbọ́ láàárín ọdún kan àti oṣù mẹ́jọ tó kọjá.

Ọ̀gbẹ́ni Du-jin Oh, tó ti ṣe agbẹjọ́rò ọ̀pọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sọ pé, “Nǹkan kan làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ń tọ́ka sí. Inú mi dùn pé iye àwọn ọkùnrin tí ilé ẹjọ́ ń dá láre ti ń pọ̀ sí i, kódà láìpẹ́ yìí, ilé ẹjọ́ gíga dá ẹnì kan láre. Lóòótọ́, àwọn tó fẹ̀sùn kan àwọn ọkùnrin yìí lè pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dá wọn láre, àmọ́ bí àwọn ilé ẹjọ́ ní South Korea ṣe ń pèrò dà lórí ọ̀rọ̀ yìí mú káwọn èèyàn túbọ̀ máa wojú Ilé Ẹjọ́ Ìjọba pé kí wọ́n ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ tó wà níwájú wọn, ìyẹn ni pé bóyá èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn ẹni mu.”

Wọ́n Ń Wá Ojútùú sí Ọ̀rọ̀ Náà

Ojú Ilé Ẹjọ́ Ìjọba làwọn èèyàn ń wò lórílẹ̀-èdè South Korea pé kí wọ́n ṣèdájọ́. Ilé ẹjọ́ yìí ló ga jù lórílẹ̀-èdè náà. Wọ́n ń gbé ọ̀rọ̀ méjèèjì tó wà nílẹ̀ wò, ìyẹn bí òfin ilẹ̀ náà ṣe fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lómìnira ẹ̀rí ọkàn, síbẹ̀, tí Òfin Iṣẹ́ Ológun tó jẹ́ ara òfin ilẹ̀ náà ní kí wọ́n fìyà jẹ àwọn tó ń lo òmìnira yẹn láti kọ̀ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ó ta ko ẹ̀sìn wọn tàbí ohun míì tí wọ́n gbà gbọ́.

Dae-il Hong, tó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà sọ pé: “Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìdílé ní South Korea ló ń retí pé kí ọ̀rọ̀ yìí lójú, kí àwọn aláṣẹ má fìyà jẹ àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí mọ́ torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, torí pé wọn ò lè fipá mú wọn ṣe ohun tí kò bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu. À ń retí ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba máa ṣe, tó máa gbe àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí, kí wọ́n lè lómìnira tó tọ́ sí wọn.”