Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

OCTOBER 12, 2016
SOUTH KOREA

Ìyà Ọ̀nà Méjì Ló Ń Jẹ Àwọn Tó Ṣẹ̀wọ̀n Torí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun, Torí Pé Ó Ti Wà Lákọọ́lẹ̀ Pé Ọ̀daràn Ni Wọ́n

Ìyà Ọ̀nà Méjì Ló Ń Jẹ Àwọn Tó Ṣẹ̀wọ̀n Torí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun, Torí Pé Ó Ti Wà Lákọọ́lẹ̀ Pé Ọ̀daràn Ni Wọ́n

Ní January 2016, Hyun-jun Gwon àti Gwang-taek Oh gba àkókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ láti lọ gbádùn ara wọn ní Japan, wọ́n wá wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ síbẹ̀ láti South Korea. Inú wọn ń dùn bí wón ṣe ń lọ, wọ́n dé ibi táwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀lú máa ń tò sí ní pápákọ̀ òfuurufú Nagoya ní Japan, wọn ò sì retí pé ẹnikẹ́ni máa yọ àwọn lẹ́nu. Àmọ́ bí wọ́n ṣe dé ọ̀dọ̀ àwọn agbófinró ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò wọ́n, torí ó wà nínú ìwé tí wọ́n fẹ́ fi wọlé pé ọ̀daràn ni wọ́n tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti ṣẹ̀wọ̀n rí.

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjèèjì ṣàlàyé pé ohun tó mú kí wọ́n rán àwọn lọ sẹ́wọ̀n ni pé àwọn kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ káwọn ṣe é, bẹ́ẹ̀, kárí ayé ni ìjọba ti fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ àwọn agbófinró náà ò jẹ́ kí wọ́n wọ orílẹ̀-èdè Japan. Léraléra ni wọ́n bẹ iléeṣẹ́ ìjọba ilẹ̀ Japan tó wà ní South Korea tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìrìnnà kí wọ́n bá wọn wá nǹkan ṣe sí i, àmọ́ ibi pẹlẹbẹ ni ọ̀bẹ ọ̀rọ̀ náà ń fi lélẹ̀. Látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí rí i pé ojú àwọn máa rí màbo torí pé àwọn dúró lórí ohun táwọn gbà gbọ́, oríṣiríṣi ọ̀nà táwọn ò retí ni á sì ti máa fìyà jẹ àwọn.

Ìyà Ọ̀nà Méjì Ló Ń Jẹ Àwọn Tó Ṣẹ̀wọ̀n

Téèyàn bá kọṣẹ́ ológun ní South Korea torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣe é, ohun méjì ló lè ṣẹlẹ̀: nínú kó pa dà dara pọ̀ mọ́ àwọn ológun tàbí kí wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n. Ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ò fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun láyè láti ṣiṣẹ́ sìnlú lọ́nà míì, ìyẹn sì ta ko àdéhùn táwọn orílẹ̀-èdè ṣe kárí ayé lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. * Èyí tó wá burú jù ni pé gbogbo ibi tí wọ́n bá dé ló máa ń wà lákọọ́lẹ̀ pé ọ̀daràn tó ti ṣẹ̀wọ̀n rí ni wọ́n, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìjọba kọ̀ láti yọ ẹ̀sùn náà kúrò lákọọ́lẹ̀. Èyí wá ń kóyà ọ̀nà méjì jẹ wọ́n láwùjọ, torí pé wọ́n tún ń hùwà àìdáa sí wọn lẹ́yìn tí wọ́n tẹ̀wọ̀n dé. Ẹ̀sùn pé “ọ̀daràn” ni wọ́n tẹ́lẹ̀ yìí ò jẹ́ káwọn èèyàn gbà wọ́n síṣẹ́, kò sì jẹ́ kí wọ́n lè rìnrìn àjò lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè bíi Japan, tó jẹ́ ibi tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ South Korea máa ń lọ.

Ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọkùnrin míì ní South Korea tí wọ́n rán lọ sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Bí àpẹẹrẹ, ní December 2011, Ọ̀gbẹ́ni Jin-mo Kang àti Kotomi ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Japan rìnrìn àjò lọ sí Japan láti lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí ìyàwó rẹ̀. Àmọ́ àwọn aláṣẹ ò jẹ́ kí Ọ̀gbẹ́ni Kang wọ orílẹ̀-èdè náà torí pé ó ti wà lákọọ́lẹ̀ pé ọ̀daràn ni torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun. Bí wọ́n ṣe dá a pa dà sí South Korea nìyẹn, tó sì wá di dandan kó fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ ní Japan. Ó tún gbìyànjú láti pa dà lọ, àmọ́ àwọn agbófinró ò tíì jẹ́ kó wọ orílẹ̀-èdè Japan.

Tiwọn Ló Yàtọ̀

Orílẹ̀-èdè Japan kì í gbà káwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun wọ orílẹ̀-èdè wọn. Àmọ́ nígbà tó yá, iléeṣẹ́ ìjọba ilẹ̀ Japan tó wà ní South Korea tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìrìnnà pa dà fún Ọ̀gbẹ́ni Oh ní ìwé ìrìnnà. Ọ̀gbẹ́ni Oh fún iléeṣẹ́ yìí ní lẹ́tà táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó wà ní Japan fi pè é wá, pé wọ́n ti ṣètò ibi tóun máa dé sí, wọ́n sì sọ pé àwọn máa bójú tó òun. Wọ́n gbà kó wọ Japan níbẹ̀rẹ̀ oṣù July 2016.

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni kì í ṣe bíi ti Japan, wọ́n gbà pé àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun kì í ṣe ọ̀daràn, wọ́n sì máa ń gbà kí wọ́n wọ orílẹ̀-èdè wọn láìka ti pé ìjọba South Korea ka àwọn ọkùnrin yìí sí “ọ̀daràn” tó ti ṣẹ̀wọ̀n rí. Ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè kan tiẹ̀ máa ń gbà wọ́n láyè kí wọ́n máa gbé nílẹ̀ wọn. Ìjọba orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, Kánádà àti Ilẹ̀ Faransé máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ ilẹ̀ South Korea tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun tó bá wá sí orílẹ̀-èdè wọn, wọn kì í fà wọ́n lé àwọn agbófinró lọ́wọ́. Ohun tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu àìpẹ́ yìí làwọn orílẹ̀-èdè yẹn ń ṣe. Àjọ náà sọ pé kí ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè “máa dáàbò bo àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun tó bá wá sí orílẹ̀-èdè wọn kí wọ́n má bàa fìyà jẹ wọ́n nílùú wọn torí pé ìjọba ilẹ̀ wọn ni ò ṣètò ọ̀nà míì téèyàn lè gbà ṣiṣẹ́ sìnlú tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.” *

Àwọn aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ ti ń kàn sí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Japan kí wọ́n lè wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà. Ọ̀gbẹ́ni André Carbonneau, tó jẹ́ agbẹjọ́rò tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kárí ayé sọ pé: “Bí Ọ̀gbẹ́ni Oh ṣe wá pa dà ráyè wọ Japan fi hàn pé ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ lọ̀rọ̀ náà, kò tó ohun tá à ń yọ àdá bẹ́. Kò ju káwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Japan ṣe òfin pé àwọn ò ka àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sí ‘ọ̀daràn’, pé ẹni àlàáfíà ni wọ́n àti pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ti ṣẹ̀wọ̀n rí, àwọn máa gbà kí wọ́n wọ orílẹ̀-èdè àwọn.”

Ṣé Orílẹ̀-èdè South Korea Máa Wá Nǹkan Ṣe Sọ́rọ̀ Yìí?

Kárí ayé làwọn èèyàn ti mọ̀ pé àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn kì í ṣe ọ̀daràn. Àtọdún 2006 ni Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè (ìyẹn ìgbìmọ̀ CCPR) ti ń sọ léraléra pé àwọn ò fara mọ́ bí orílẹ̀-èdè South Korea ṣe ń fi àwọn èèyàn sẹ́wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn. Ìgbìmọ̀ CCPR sọ pé ṣe ni ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea “ń ti àwọn èèyàn mọ́lé láìnídìí” bí wọ́n ṣe ń fi àwọn èèyàn sẹ́wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn. Ìgbìmọ̀ yìí sì rọ ìjọba pé kí wọ́n ṣòfin tó máa fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ohun kan tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá jẹ́ kó ṣe é. Nínú àwọn ẹjọ́ tí Ìgbìmọ̀ CCPR dá, wọ́n sọ fún ìjọba ilẹ̀ South Korea pé kí wọ́n fagi lé àkọsílẹ̀ èyíkéyìí tó bá sọ pé ọ̀daràn ni àwọn tí wọ́n ti rán lọ sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. *

Síbẹ̀, orílẹ̀-èdè South Korea ò ṣe ohun tí Ìgbìmọ̀ CCPR ní kí wọ́n ṣe. Àmọ́, ó di dandan kí wọ́n ṣe ohun tí ìgbìmọ̀ yìí sọ tó bá tiẹ̀ ta ko òfin orílẹ̀-èdè wọn, torí pé South Korea wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights àti Àfikún Ìlànà rẹ̀.

Tí ìjọba South Korea ò bá tẹ̀ lé ohun tí ìjọba àpapọ̀ fi lọ́lẹ̀ kárí ayé, kí wọ́n sì gbà pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ohun kan tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá jẹ́ kó ṣe, ọ̀pọ̀lọpọ̀ aráàlú ló tún ṣì máa ṣẹ̀wọ̀n, àwọn èèyàn á sì máa yẹ̀yẹ́ wọn torí ìjọba ti bà wọ́n lórúkọ jẹ́ pé ọ̀daràn ni wọ́n. * Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń retí ọjọ́ tí ìjọba ilẹ̀ South Korea máa fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ohun kan tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kó ṣe, tí wọn ò sì ní máa fẹ̀sùn ọ̀daràn kan irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Ní báyìí ná, àwọn ọmọ ilẹ̀ South Korea, bí Ọ̀gbẹ́ni Gwon àti Ọ̀gbẹ́ni Oh, ń retí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Japan máa ṣòfin tó máa jẹ́ kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ráyè wọ orílẹ̀-èdè Japan.

^ ìpínrọ̀ 5 Lọ́wọ́lọ́wọ́, South Korea wà lára àwọn orílẹ-èdè mẹ́rin tó ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó ń fa àwọn èèyàn wọṣẹ́ ológun ló ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú lọ́nà kan tàbí òmíràn tó yàtọ̀ sí iṣẹ́ ológun fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

^ ìpínrọ̀ 9 Wo Resolution 24/17 “Conscientious objection to military service,” tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ṣe ní October 8, 2013.

^ ìpínrọ̀ 12 Wo Communications No. 1642-1741/2007, Jeong et al v. The Republic of Korea, àwọn Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ náà ṣe ní March 24, 2011.

^ ìpínrọ̀ 14 Láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn, 2,701 ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìjọba South Korea ti rán lọ sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.