Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

SOUTH KOREA

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè South Korea

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè South Korea

Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà nílẹ̀ Korea, tí wọ́n sì ti ń ṣe ẹ̀sìn wọn láìsí ìdíwọ́ kankan. Àmọ́ ìṣòro tó le jù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kojú ní orílẹ̀-èdè South Korea ni bí ìjọba ò ṣe yéé pe àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lẹ́jọ́.

Ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ò fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kó ṣe é, wọn ò sì ṣòfin pé èèyàn lè ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun. Torí náà, ẹ̀wọ̀n ọdún kan ààbọ̀ ni wọ́n máa ń rán àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó bá kọ̀ torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe é lọ. Ogójì [40] sí àádọ́ta [50] ọkùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n máa ń rán lọ sẹ́wọ̀n lóṣooṣù. Ìyà ọ̀nà méjì làwọn ọkùnrin yìí wá ń jẹ torí pé tí wọ́n bá ti kúrò lẹ́wọ̀n, ó ti máa ń wà lákọọ́lẹ̀ pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun, pé ọ̀daràn sì ni wọ́n. Èyí lè mú kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máà ríṣẹ́, wọ́n sì lè fi àwọn ohun kan dù ú láwùjọ.

Àwọn míì tó tún máa ń níṣòro lórí ọ̀rọ̀ yìí ni àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀, tí wọ́n ti lo àkókò tí ìjọba ní kí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ológun pé àmọ́ tí wọ́n ti wá gba ohun tí Bíbélì sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa, ká má sì kọ́ṣẹ́ ogun. Torí pé ìjọba ṣì máa ń pè wọ́n nígbàkigbà pé kí wọ́n wá ṣèrànwọ́ lójú ogun, léraléra ni wọ́n máa ń pe àwọn ọkùnrin yìí lẹ́jọ́ torí wọn kọ̀ láti máa báṣẹ́ ọ̀hún lọ, wọ́n sì máa ń bu owó ìtanràn lé wọn.

Ìpinnu tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ni Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ti ṣe lórí bí ìjọba South Korea ṣe ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lójú, wọ́n sì sọ pé ṣe ni ìjọba ń “tì wọ́n mọ́lé láìnídìí.” Ìgbìmọ̀ náà tún sọ pé “ó di dandan” kí orílẹ̀-èdè South Korea “máà jẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ mọ́” lọ́jọ́ iwájú. Tí wọ́n bá yanjú ọ̀rọ̀ yìí, ìyẹn fi hàn pé wọ́n gbà pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohun tó bá bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu, kí wọ́n sì ṣe ẹ̀sìn tó bá wù wọ́n ní South Korea.