Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

SOUTH KOREA

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lórílẹ̀-èdè South Korea, wọ́n sì lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn, àfi àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Látìgbà tí Ogun Orílẹ̀-èdè Korea ti jà títí dòní, ìjọba ilẹ̀ South Korea ṣì ń fẹ̀sùn kan àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun, ìjọba ò sì pèsè ohunkóhun tí wọ́n lè ṣe dípò kí ọ̀rọ̀ náà lè lójútùú. Kí ló ti wá ṣẹlẹ̀ látìgbà yẹn? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún [19,000] ni ìjọba ilẹ̀ South Korea ti rán lọ sẹ́wọ̀n, àpapọ̀ ọdún tí gbogbo wọn sì lò lẹ́wọ̀n torí wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì [36,000].

Ohun tí Ìjọba Àpapọ̀ Sọ Nípa Ẹ̀tọ́ Láti Ṣe Ohun tí Ẹ̀rí Ọkàn Ẹni Ò Gbà Láyè

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè (ìyẹn CCPR) máa ń rí sí i pé àwọn orílẹ̀-èdè tó ti tọwọ́ bọ àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights (ICCPR), èyí tó ń dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn aráàlú, ń tẹ̀ lé àdéhùn náà. Léraléra ni Ìgbìmọ̀ náà ti sọ fún ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea * pé wọ́n ń fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà láyè láti ṣe ohun kan dù wọ́n, torí pé ṣe ni wọ́n ń dá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́bi, tí wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ní January 14, 2015, Ìgbìmọ̀ náà ṣe ìpinnu karùn-ún tí wọ́n fi dá ìjọba ilẹ̀ South Korea lẹ́bi lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ohun tí wọ́n ti ń sọ tẹ́lẹ̀ nínú àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe kọjá náà ni ìpinnu tọ̀tẹ̀ yìí dá lé, wọ́n ní ìjọba ilẹ̀ South Korea ti fi ẹ̀tọ́ àwọn àádọ́ta [50] Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n dù wọ́n, ìyẹn “ẹ̀tọ́ láti ní èrò tó wuni, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá fẹ́ àti ẹ̀sìn tó wuni.” Ohun tí wọ́n fi parí ọ̀rọ̀ wọn ni pé ìjọba jẹ̀bi “ìtinimọ́lé láìnídìí” torí pé wọ́n fìyà jẹ àwọn ọkùnrin náà lórí ẹ̀tọ́ wọn, ìyẹn ẹ̀tọ́ tí àdéhùn ICCPR sọ pé àwọn ọkùnrin náà ní.

Lẹ́yìn tí Ìgbìmọ̀ náà ṣàyẹ̀wò gbogbo àkọsílẹ̀ tó dá lórí ọwọ́ tí ìjọba South Korea fi mú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, Ìgbìmọ̀ náà sọ ibi tí wọ́n parí èrò sí ní November 3, 2015. Wọ́n rọ ìjọba pé kí wọ́n dá gbogbo àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun tí wọ́n tì mọ́lé sílẹ̀, kí wọ́n fagi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, kí wọ́n san gbogbo owó gbà-máà-bínú tó yẹ, kí wọ́n sì ṣòfin tó fàyè gba iṣẹ́ àṣesìnlú. Wọ́n ní kí ìjọba “ṣe gbogbo ohun tí Ìgbìmọ̀ náà sọ nínú àwọn Ìpinnu tí wọ́n ti ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí.”

Ohun Táwọn Aráàlú South Korea Ń Sọ

Ìjọba ò rímú mí torí wọn ò yé sọ fún wọn kí wọ́n ṣòfin tó máa fàyè gba àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun láti máa ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú. Àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ kan ti kéde pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án tó kọ iṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe é kò jẹ̀bi. Àwọn ilé ẹjọ́ láwọn àgbègbè kan ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ Ilé Ẹjọ́ Ìjọba South Korea, nígbà tó sì di July 9, 2015, Ilé Ẹjọ́ náà ṣe ìgbẹ́jọ́ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá bí ìjọba ṣe ń fọwọ́ rọ́ ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn bá fẹ́ sẹ́yìn yìí bá òfin mu tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àmọ́ ní ọdún 2004 àti 2011, Ilé Ẹjọ́ náà ti dájọ́ pé ohun tí Òfin Iṣẹ́ Ológun sọ láìfi ti ẹ̀rí ọkàn pè tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ ológun kò ta ko òfin ìjọba. À ń retí ìpinnu tí wọ́n máa ṣe láìpẹ́.

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

 1. April 30, 2017

  Àpapọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà 401 ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

 2. November 3, 2015

  Ìgbìmọ̀ CCPR sọ ibi tí wọ́n parí èrò sí, wọ́n rọ ìjọba ilẹ̀ South Korea pé kí wọ́n ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú.

 3. July 9, 2015

  Ilé Ẹjọ́ Ìjọba wò ó bóyá àwọn ohun kan tó wà tí Òfin Iṣẹ́ Ológun sọ tó ta ko òfin ìjọba.

 4. January 14, 2015

  Ìgbìmọ̀ CCPR ṣe Ìpinnu tó fi hàn pé ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ti rú òfin tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 18 (ìyẹn ẹ̀tọ́ láti ní èrò tó wuni, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá fẹ́ àti ẹ̀sìn tó wuni) àti Àpilẹ̀kọ 9 (tí kò fàyè gba ìtinimọ́lé láìnídìí) tó wà nínú àdéhùn ICCPR torí pé wọ́n fi ẹ̀tọ́ àwọn àádọ́ta [50] Ẹlẹ́rìí tí wọ́n sọ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà á dù wọ́n, wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé.

 5. June 30, 2014

  Ẹjọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n [28] tó dá lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ló ṣì wà ní Ilé Ẹjọ́ Ìjọba; 618 ọkùnrin ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n.

 6. January 28, 2014

  Ààrẹ ṣètò pàtàkì kan pé kí wọ́n yọ oṣù kan tàbí méjì kúrò lára iye ọjọ́ tí àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún [100] máa lò lẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun; èèyàn 513 ló ṣì wà lẹ́wọ̀n ní January 31.

 7. November 2013

  Àpapọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà 599 ni wọ́n tì mọ́lé torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

 8. April 2013

  Ìdá méje nínú mẹ́wàá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n ni wọn ò fi síbi táwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù wà, yàrá táwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn wà ni wọ́n fi wọ́n sí.

 9. October 25, 2012

  Ìgbìmọ̀ CCPR ṣe Ìpinnu tó fi hàn pé ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ti rú òfin tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 18 (ìyẹn ẹ̀tọ́ láti ní èrò tó wuni, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá fẹ́ àti ẹ̀sìn tó wuni) tó wà nínú àdéhùn ICCPR torí pé wọ́n fi ẹ̀tọ́ àwọn 388 Ẹlẹ́rìí tí wọ́n sọ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà á dù wọ́n.

 10. August 30, 2011

  Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ṣe fi hàn pé kò ta ko Òfin ilẹ̀ Korea láti fìyà jẹ àwọn tó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè.

 11. March 24, 2011

  Ìgbìmọ̀ CCPR ṣe Ìpinnu tó fi hàn pé ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ti rú òfin tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 18 nínú àdéhùn ICCPR torí pé wọ́n fi ẹ̀tọ́ àwọn ọgọ́rùn-ún [100] Ẹlẹ́rìí tí wọ́n sọ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà á dù wọ́n.

 12. January 15, 2009

  Àjọ tó ń ṣèwádìí nípa àwọn tó kú nínú iṣẹ́ ológun gbé èsì ìwádìí wọn jáde, ó sì fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea lọ́wọ́ sí ikú àwọn ọ̀dọ́kùnrin márùn-ún kan láàárín ọdún 1975 sí 1985 tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

 13. December 2008

  Ìjọba ilẹ̀ South Korea pèrò dà nípa ètò tí wọ́n ń ṣe láti jẹ́ kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun máa ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú.

 14. September 18, 2007

  Ilé Iṣẹ́ Ìjọba South Korea tó ń rí sí Ọ̀rọ̀ Ààbò kéde pé ìjọba ti ń ṣètò láti jẹ́ kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀sìn wọn máa ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú, wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn máa ṣàtúnṣe sí òfin iṣẹ́ ológun àti òfin tó kan àwọn ọmọ ogun tí wọ́n máa ń ké sí láti lọ sójú ogun tí wọ́n bá nílò wọn.

 15. November 3, 2006

  Ìgbìmọ̀ CCPR ṣe Ìpinnu tó fi hàn pé ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ti rú òfin tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 18 nínú àdéhùn ICCPR torí pé wọ́n fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì tí wọ́n sọ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà á dù wọ́n.

 16. August 26, 2004

  Ilé Ẹjọ́ Ìjọba sọ pé ó bófin mu láti máa fìyà jẹ àwọn tó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà á.

 17. 2001

  Iléeṣẹ́ tó ń gba àwọn èèyàn sí iṣẹ́ ológun ṣíwọ́ fífi ipá múni wọṣẹ́ ológun, wọ́n sì dín iye ọdún tí ẹni tí wọ́n bá fi sẹ́wọ̀n gbọ́dọ̀ lò kù látorí mẹ́ta sí ọdún kan àtààbọ̀.

 18. December 1, 1985

  Torí ìwà ipá àti ìwà ìkà tí àwọn ológun hù sí Kim, Young-geun, ó kú sẹ́wọ̀n tí wọ́n rán an lọ torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.

 19. August 17, 1981

  Torí ìwà ipá àti ìwà ìkà tí àwọn ológun hù sí Kim, Sun-tae, ó kú sẹ́wọ̀n tí wọ́n rán an lọ torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.

 20. March 28, 1976

  Jeong, Sang-bok kú lẹ́yìn tí àwọn ológun lù ú nílùkulù, tí wọ́n sì ṣe é bí ọṣẹ ṣe ń ṣe ojú torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.

 21. March 19, 1976

  Lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá lu Lee, Choon-gil nílùkulù torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun, ọ̀kan lára ẹ̀yà ara tí ẹ̀jẹ̀ máa ń wà nínú rẹ̀ bẹ́, ó sì kú.

 22. November 14, 1975

  Kim, Jong-sik kú lẹ́yìn tí àwọn ológun lù ú nílùkulù, tí wọ́n sì dá a lóró torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.

 23. 1975

  Ààrẹ Park Jeong-hee sọ pé kí wọ́n máa fi dandan mú àwọn èèyàn wọ iṣẹ́ ológun, ẹnikẹ́ni ò sì gbọ́dọ̀ kọ̀ láti ṣe é bó ṣe yẹ. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fipá mú àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ síbi tí wọ́n á ti máa kọ́ṣẹ́ ológun.

 24. January 30, 1973

  Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé òfin àrà ọ̀tọ̀ kan láti fìyà jẹ ẹni tó bá rú Òfin Iṣẹ́ Ológun. Tẹ́lẹ̀, ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta ló pọ̀ jù tí wọ́n máa ń rán àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lọ, àmọ́ wọ́n sọ ọ́ di mẹ́wàá. Wọ́n ń fi àwọn kan sẹ́wọ̀n léraléra.

 25. 1953

  Ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n.

^ ìpínrọ̀ 4 South Korea wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó fọwọ́ sí àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights (ICCPR), wọ́n sì fọwọ́ sí àfikún ìlànà àkọ́kọ́ nínú àdéhùn ICCPR, èyí tó fọwọ́ sí i káwọn ọmọ ilẹ̀ South Korea kọ̀wé sí Ìgbìmọ̀ CCPR tí wọ́n bá fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn wọn dù wọ́n, torí ó ta ko àdéhùn ICCPR láti ṣe bẹ́ẹ̀.