Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ọ̀RÀN ÒFIN

Ọ̀ràn Ẹjọ́ ní South Korea

MARCH 7, 2017

Ìjọba South Korea Ń Fìyà tí Kò Tọ́ Jẹ Dong-hyuk Shin

Wọ́n ń fìyà tí kò tọ́ jẹ Ọ̀gbẹ́ni Shin torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun tí wọ́n pè é fún, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n ń fi òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn dù ú.

JANUARY 25, 2017

“Ìpinnu Tó Dáa Jù tí Ilé Ẹjọ́ Ṣe Lọ́dún Yìí”

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Gwangju dá àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́ta tó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun láre. Àwọn ará South Korea sì ń retí ìpinnu tí ilé ẹjọ́ tó ga jù lórílẹ̀-èdè náà máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ tó ti wà nílẹ̀.

JANUARY 25, 2017

Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Rọ Ìjọba Pé Kí Wọ́n Má Ṣe Fi Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn Du Aráàlú

Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè South Korea rọ ìjọba pé kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní lábẹ́ òfin dù wọ́n, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.