Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

SIRI LÁŃKÀ

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Siri Láńkà

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Siri Láńkà

Àtọdún 1910 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ẹ̀sìn wọn lórílẹ̀-èdè Siri Láńkà. Wọ́n ṣí ọ́fíìsì kan síbẹ̀ lọ́dún 1952 láti máa fi bójú tó iṣẹ́ wọn, wọ́n sì forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lọ́dún 1981, wọ́n pè é ní Watch Tower Bible and Tract Society of Lanka. Wọ́n sì lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn.

Olórí ìṣòro táwọn Ẹlẹ́rìí ní lórílẹ̀-èdè yìí ni pé àwọn jàǹdùkú máa ń ṣe wọ́n níkà, bẹ́ẹ̀, àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ẹlẹ́sìn Búdà tí wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ló ń rúná sí i. Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ni àwọn aláṣẹ tún máa ń dá kún un torí pé wọn kì í gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí, wọn kì í sì í pe àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ibi yìí lẹ́jọ́. Lọ́dún 2014, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè dá sí i, wọ́n rọ ìjọba pé kí wọ́n dáwọ́ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí dúró, kí wọ́n sì rí i pé gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwà ipá táwọn jàǹdùkú hù sáwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké, bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì ti fẹjọ́ rẹ̀ sùn dé ilé ẹjọ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí ti kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí àwọn ilé ẹjọ́ gíga, wọ́n sì ti kọ̀wé sáwọn aláṣẹ ní Siri Láńkà pé kí wọ́n wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń retí pé lọ́jọ́ iwájú, wọ́n máa lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn lórílẹ̀-èdè Siri Láńkà láìsí ìbẹ̀rù pé àwọn agbawèrèmẹ́sìn máa yọ wọ́n lẹ́nu.