Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

SINGAPORE

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Ìjọba orílẹ̀-èdè Singapore sọ pé dandan ni káwọn èèyàn wọṣẹ́ ológun, wọn ò sì gbà pé ẹnì kan lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò gba òun láyè. Ẹ̀ẹ̀mejì tẹ̀ léra ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣẹ̀wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun, àpapọ̀ oṣù mọ́kàndínlógójì [39] sì ni wọ́n máa ń lò lẹ́wọ̀n.

Tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] lórílẹ̀-èdè Singapore, wọ́n máa ní kó wá wọṣẹ́ ológun. Tó bá kọ̀, torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣe é, wọ́n á fi sí àtìmọ́lé ní àgọ́ àwọn ológun fún oṣù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15]. Tó bá ti lo ọjọ́ ẹ̀ pé lẹ́wọ̀n, wọ́n á dá a sílẹ̀. Wọ́n á wá pàṣẹ pé kó wọ aṣọ ológun lójú ẹsẹ̀, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun. Tó bá tún kọ̀ pé òun ò ṣe, wọ́n á ní kó fojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n á sì fi sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́rìnlélógún [24].

Orílẹ̀-èdè Singapore Ò Gbà Láti Ṣe Ohun tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Ní Kí Wọ́n Ṣe

Ọjọ́ pẹ́ tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ti ń rọ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ wọn pé “kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun dù wọ́n torí pé ẹ̀tọ́ láti ní èrò tó wuni, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni gbà láyè àti ẹ̀sìn tó wuni ni wọ́n ń tẹ̀ lé, ìyẹn sì bófin mu torí ó wà nínú ìwé Universal Declaration of Human Rights.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Singapore ti wà lábẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè látọdún 1965, kò fara mọ́ ohun tí àjọ náà sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Nínú lẹ́tà tí òṣìṣẹ́ ìjọba kan lórílẹ̀-èdè Singapore kọ sí Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ní April 24, 2002, ó sọ pé “tí ohun tí ẹnì kan gbà gbọ́ tàbí tó ń ṣe bá ti ta ko [ẹ̀tọ́ láti gbèjà orílẹ̀-èdè], ẹ̀tọ́ tí orílẹ̀-èdè ní láti pèsè ààbò ló gbọ́dọ̀ gbawájú.” Òṣìṣẹ́ náà sojú abẹ níkòó pé, “A ò fara mọ́ ọn pé ibi gbogbo láyé ni àwọn èèyàn ti lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè.”

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

 1. March 17, 2017

  Àpapọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun.

 2. November 2013

  Àpapọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlógún [18] ni wọ́n tì mọ́lé torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun.

 3. April 24, 2002

  Òṣìṣẹ́ ìjọba fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé orílẹ̀-èdè Singapore ò fara mọ́ ọn pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ò gbà á láyè.

 4. February 1995

  Wọ́n túbọ̀ ń ká àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Singapore tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò, wọ́n sì ń mú wọn.

 5. August 8, 1994

  Ilé Ẹjọ́ Gíga lórílẹ̀-èdè Singapore ò fọwọ́ sí ohun táwọn Ẹlẹ́rìí béèrè.

 6. January 12, 1972

  Lẹ́yìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ìjọba orílẹ̀-èdè Singapore yọ orúkọ wọn kúrò.