Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

RÙWÁŃDÀ

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Rùwáńdà

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Rùwáńdà

Àtọdún 1970 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ẹ̀sìn wọn lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà. Wọ́n forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1992, ìjọba sì ní kí wọ́n tún un ṣe lọ́dún 2002. Àwọn èèyàn mọ àwọn Ẹlẹ́rìí dáadáa pé wọn kì í dá sí òṣèlú, wọ́n sì lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Nígbà ìpakúpa tó wáyé lọ́dún 1994, wọn ò lọ́wọ́ sí i, kódà, ṣe ni wọ́n tún fẹ̀mí ara wọn wewu torí àwọn ẹlòmíì. Àmọ́ àwọn kan máa ń ṣe ẹ̀tanú sí àwọn Ẹlẹ́rìí títí dòní torí pé wọn kì í dá sí òṣèlú.

Àwọn ọ̀gá iléèwé kan máa ń lé àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà níléèwé torí pé wọn kì í lọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ orílẹ̀-èdè àti ti ìsìn. * Bákan náà, ìjọba sọ pé àwọn olùkọ́ gbọ́dọ̀ máa gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ológun, kí wọ́n sì máa kọ orin orílẹ̀-èdè. Torí ìyẹn, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olùkọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ wọn. Lọ́dún 2010, ìjọba orílẹ̀-èdè Rùwáńdà ní kí gbogbo òṣìṣẹ́ ìjọba lọ́wọ́ sí ayẹyẹ ìbúra kan tí wọ́n ti máa kí àsìá. Bó ṣe di pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba nìyẹn.

Láìka gbogbo ìṣòro yìí sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà ṣì mọrírì òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Wọ́n retí pé láìpẹ́, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rùwáńdà máa rí i pé báwọn ò ṣe dá sí ọ̀sèlú kò túmọ̀ sí pé àwọn ta ko ìjọba.

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé téèyàn bá ń lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ orílẹ̀-èdè, ṣe lèèyàn ń jọ́sìn orílẹ̀-èdè rẹ̀, ó sì ta ko òfin tí Ọlọ́run fún wa pé òun nìkan ni ká máa jọ́sìn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí kì í lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ yìí, wọ́n gbà pé àwọn míì lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́.