Ní September 23, 2016, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Tver ní Moscow ti sún ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè síwájú, èyí tó dá lórí ìkìlọ̀ táwọn aláṣẹ fún wọn pé àwọn máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn lórílẹ̀-èdè náà pa. Ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú ọjọ́ tó yẹ kí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ náà, Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà kọ̀wé sí ilé ẹjọ́ pé àwọn ò fara mọ́ ọn, wọ́n sì fi ìwé kan tó ní ojú ìwé igba [200] ránṣẹ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí wá kọ̀wé sí ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n fún àwọn ní àkókò láti ka ohun tó wà nínú ìwé náà, adájọ́ sì sọ pé òun sún ẹjọ́ sí October 12, 2016. Ilé ẹjọ́ máa wá gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì máa wò ó bóyá ìkìlọ̀ táwọn aláṣẹ fún àwọn Ẹlẹ́rìí pé àwọn máa ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn pa bófin mu àbí kò bófin mu.