Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

JULY 22, 2016
RUSSIA

Ilé Ẹjọ́ Ti Sún Ẹjọ́ tí Wọ́n Fẹ́ Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí tí Wọ́n Fẹ́ Tì Pa sí Oṣù September

Ilé Ẹjọ́ Ti Sún Ẹjọ́ tí Wọ́n Fẹ́ Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí tí Wọ́n Fẹ́ Tì Pa sí Oṣù September

Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Tver nílùú Moscow gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn tọ́rọ̀ kàn, lórí ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Agbẹjọ́rò Àgbà tó kọ lẹ́tà sí àwọn Ẹlẹ́rìí pé àwọn máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn pa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Àwọn lọ́gàá-lọ́gàá tí wọ́n ń ṣojú oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè ló wà nílé ẹjọ́ lọ́jọ́ yẹn. Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ gbọ́ tẹnu àwọn méjèèjì, wọ́n sún ẹjọ́ náà sí September 23, 2016. Ìgbà yẹn gan-an ni ilé ẹjọ́ máa jókòó gbọ́ ẹjọ́ náà.

Ìjọba tún gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó ṣeé ṣe kó pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn. Wọ́n ṣàtúnṣe sí Òfin Ìjọba lórí ọ̀rọ̀ Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn àti báwọn ẹlẹ́sìn ṣe ń kóra jọ láti ṣèsìn, òfin yìí sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní July 20, 2016. À ń retí bí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe máa lo òfin tuntun yìí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.