Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JUNE 28, 2016
RUSSIA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Retí Ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Máa Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn Tó Wà ní Rọ́ṣíà tí Àwọn Aláṣẹ Fẹ́ Tì Pa

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Retí Ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Máa Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn Tó Wà ní Rọ́ṣíà tí Àwọn Aláṣẹ Fẹ́ Tì Pa

Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Tver nílùú Moscow máa tó dá ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kọ̀wé pè nígbà táwọn aláṣẹ ń halẹ̀ ṣáá pé wọ́n máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn lórílẹ̀-èdè náà pa. Agbẹjọ́rò Àgbà kìlọ̀ fún wọn pé àwọn máa ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pa torí pé iṣẹ́ “agbawèrèmẹ́sìn” ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ kí ilé ẹjọ́ fagi lé ohun tí Agbẹjọ́rò Àgbà náà sọ, torí pé ìgbésẹ̀ tó fẹ́ gbé yẹn ò ní jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí lómìnira ẹ̀sìn tí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí. Ohun míì tún ni pé ṣe ni agbẹjọ́rò yìí mọ̀ọ́mọ̀ ṣi òfin orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lò, èyí tó dá lórí ọ̀rọ̀ àwọn agbawèrèmẹ́sìn.

Ọ̀gbẹ́ni Vasiliy Kalin, tó jẹ́ aṣojú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà sọ pé: “A ò ṣe ohun tó jẹ mọ́ tàwọn agbawèrèmẹ́sìn rí. A retí pé ilé ẹjọ́ ò ní jẹ́ kí wọ́n rẹ́ wa jẹ.”