Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

OCTOBER 14, 2016
RUSSIA

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pè Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn tí Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà Fẹ́ Tì Pa

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pè Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn tí Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà Fẹ́ Tì Pa

Ní October 12, 2016, Ilé Ẹjọ́ Tverskoy nílùú Moscow fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè láti mọ̀ bóyá ó bófin mu àbí kò bófin mu bí Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà ṣe sọ pé àwọn máa ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn tó wà ní tòsí ìlú St. Petersburg pa. Lẹ́tà tí Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà kọ ní March 2, 2016 láti fi kìlọ̀ fún wọn sọ pé àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan làwọn fẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ “agbawèrèmẹ́sìn,” kì í ṣe Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn. Àmọ́ torí pé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà ló ń bójú tó iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, òun ló máa forí fá a. Bẹ́ẹ̀, ohun tó mú kí wọ́n fẹ̀sùn “agbawèrèmẹ́sìn” kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ̀sùn kan tí àwọn aláṣẹ ti kọ́kọ́ lọ́ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ àtàwọn irọ́ tí wọ́n hùmọ̀ lóríṣiríṣi. Nígbà yẹn, adájọ́ ò gbà kí àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn mú ẹlẹ́rìí wá sílé ẹjọ́, kò sì gbà kí wọ́n fi fídíò tí wọ́n lè fi gbèjà ara wọn hàn, pé ṣe ni àwọn kan lọ fi àwọn ìwé tí òfin kà sí ẹrù agbawèrèmẹ́sìn sínú ilé ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọn ò sí níbẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún máa kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Moscow. Tí ilé ẹjọ́ yìí bá dá wọn lẹ́bi, a jẹ́ pé ohun tí Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà sọ máa ṣẹlẹ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ kó nira fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà láti lómìnira ẹ̀sìn. Tọ́rọ̀ bá sì wá rí bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú irọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ́ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́sẹ̀ yìí láti fi hàn pé “agbawèrèmẹ́sìn” ni wọ́n, Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà lè bẹ̀rẹ̀ ètò lórí ìgbẹ́jọ́ tó máa yọrí sí títi Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà pa.