Kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tún lè fòfin de òmìnira ẹ̀sìn, wọ́n ti gbé ẹ̀sùn kan dìde kí wọ́n lè kéde pé ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. March 15, 2016 ni wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́. Lọ́dún tó kọjá, àwọn agbófinró tó ń rí sí ohun tó ń wọlé tó ń jáde lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ohun tó ṣàjèjì, wọ́n ní wọn ò gbọ́dọ̀ kó àwọn ẹ̀dà Bíbélì yìí wọ orílẹ̀-èdè náà. Ìgbésẹ̀ tuntun tí wọ́n gbé yìí ò bọ̀wọ̀ fún ìwé mímọ́ tó jẹ́ ti àwọn Kristẹni.

Òfin ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pe Bíbélì ní ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn. Àmọ́, agbẹjọ́rò tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìkẹ́rù ní Leningrad-Finlyandskiy ń fi ohun tí ẹnì kan tí kò mọ̀ nípa èdè sọ ṣe àwíjàre. Tí ilé ẹjọ́ bá dá agbẹjọ́rò yìí láre, wọ́n lè fòfin de pípín Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.