Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

SEPTEMBER 15, 2015
RUSSIA

Wọ́n Ní Káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pa Dà Sílé Ẹjọ́ Nílùú Taganrog—Ìgbà Wo La Máa Bọ́ Báyìí?

Wọ́n Ní Káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pa Dà Sílé Ẹjọ́ Nílùú Taganrog—Ìgbà Wo La Máa Bọ́ Báyìí?

Wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbọ́ ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ń tún gbọ́ nílùú Taganrog tán. Ó ti lé lọ́dún méjì táwọn Ẹlẹ́rìí ti ń fojú ba ilé ẹjọ́ bí ọ̀daràn torí pé wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ó ṣeé ṣé kí wọ́n rán àwọn kan lọ sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n ní káwọn míì sanwó ìtanràn gọbọi. Àkóbá wo ni ẹjọ́ tó ń falẹ̀ yìí ti ṣe fáwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n pè lẹ́jọ́? Tí ilé ẹjọ́ bá pa dà dá wọn lẹ́bi, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wọn?