Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MAY 30, 2017
RUSSIA

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́run Ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní July 17, 2017

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́run Ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní July 17, 2017

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́run nítorí pé ilé ẹjọ́ gíga jù lọ fòfin de ìjọsìn wa. Ní April 20, àdájọ́ Yuriy Ivanenko dájọ́ pé ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo àjọ tá a gbé kalẹ̀ lábẹ́ òfin lórílẹ̀ èdè Rọ́ṣíà. Àwọn adájọ́ mẹ́ta ní ẹ̀ka kòtẹ́milọ́rùn ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ló máa tún ẹjọ́ yìí gbé yẹ̀ wò ní July 17, 2017.

Ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ nínú ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà ni pé kí wọ́n yí ìdájọ́ tí wọ́n ṣe fún wa pa dà. Nítorí pé kò sí ẹ̀rí tó jóòótọ́ láti fi ti ẹjọ́ tí wọ́n dá fún wa lẹ́yìn àti pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe agbawèrèmẹ́sìn. Ohun míì tún ni pé ẹ̀sùn tí ìjọba fi kàn wá, tí wọ́n sì fi ṣenúnibíni sí wa nígbà Soviet Union náà ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fi kàn wá tí wọ́n sì fi dá wa lẹ́jọ́ báyìí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé nígbà Soviet Union yẹn, ìjọba yí ẹ̀sùn náà pa dà, wọ́n sọ pé a ò jẹ̀bi torí pé àwọn ẹ̀sùn náà ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ́. Láfìkún sí ìyẹn, ẹjọ́ tí wọ́n dá yìí ta ko òfin orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tó fàyè gba òmìnira ẹ̀sìn.

Ẹjọ́ tí wọ́n dá fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ti fa ọgbẹ́ ọkàn fún wa gan-an torí ó máa ń mú wa rántí bí Ìjọba Kọ́múníìsì ṣe ni wá lára. Àwọn aláṣẹ ń fi ìya jẹ àwọn ẹlẹ́rìí kan lórí ẹ̀sun “agbawèrèmẹ́sìn,” iṣẹ́ ti bọ́ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí míì lọ́wọ́, àwọn olùkọ́ míì máa ń fi àwọn ọmọ wa ṣẹ̀sín nílé ìwé níṣojú àwọn ọmọ ilé ìwé ẹlẹgbẹ́ wọn, àwọn tí kò sì nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlérìí lọ ń bá àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa jẹ́, kódà wọ́n ti ẹ̀ tún jù bọ́mbù sí ilé àwọn Ẹlẹ́rìí méjì, wọ́n jó àwọn ilé náà kanlẹ̀.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé retí pé kí àwọn adájọ́ tó máa tún ẹjọ́ náà gbé yẹ̀ wò rí àwọn ẹ̀sùn tí kò jóòótọ́ tí wọ́n fi kàn wá yìí, kí wọ́n sì yíi pa dà, ká lè ní omìnira ẹ̀sìn, ká sì bọ́ lọ́wọ́ ewu ní orílè-èdè Rọ́ṣíà.