Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JANUARY 16, 2017
RUSSIA

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Rọ́ṣíà Fagi Lé Ẹjọ́ Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pè Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Rọ́ṣíà Fagi Lé Ẹjọ́ Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pè Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn

Ní January 16, 2017, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Moscow fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè lórí ọ̀rọ̀ ohun tí Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà sọ pé àwọn máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí pa. Adájọ́ mẹ́ta ló gbọ́ ẹjọ́ yìí, wọ́n kọ́kọ́ fagi lé gbogbo ìwé táwọn agbẹjọ́rò tó ń gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ, wọ́n wá gba àkókò ìsinmi fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n wá ṣèdájọ́. Wọ́n sọ pé àwọn fọwọ́ sí ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Ìpínlẹ̀ ní Tverskoy ṣe ní October 12, 2016, èyí tó gbe Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà. March 2, 2016 ni Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà kìlọ̀ fáwọn Ẹlẹ́rìí pé àwọn máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn, wọ́n sì ti wá lè ṣe é báyìí. Àmọ́ a ò tíì mọ ipa tí ọ̀rọ̀ yìí máa ní lórí òmìnira ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.