Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

APRIL 7, 2017
RUSSIA

Ọjọ́ Kẹta Rèé tí Wọ́n Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Táwọn Aláṣẹ Fẹ́ Fòfin Dè

Ọjọ́ Kẹta Rèé tí Wọ́n Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Táwọn Aláṣẹ Fẹ́ Fòfin Dè

Ọjọ́ kẹta rèé tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti ń gbọ́ ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táwọn aláṣẹ fẹ́ fòfin dè ní Rọ́ṣíà. Ara àwọn tí wọ́n pè wá jẹ́rìí ni àwọn méjì nínú àwọn tó ń darí ohun tó ń lọ ní Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn méjèèjì jẹ́rìí ta ko Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Sergey Cherepanov sọ pé òun ò fara mọ́ ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáwọ́ nínú ìwà agbawèrèmẹ́sìn tí wọ́n ń hù ní Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn torí pé ó ta ko òfin. Bẹ́ẹ̀, Ilé Iṣẹ́ náà ò ṣàlàyé rí nípa bí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà ṣe ṣohun tó ta ko òfin, àbí kí wọ́n sọ bí wọ́n ṣe máa jáwọ́ tó bá jẹ́ pé wọ́n ń ṣohun tó ta ko òfin lóòótọ́. Ẹnì kejì tí wọ́n pè jẹ́rìí ni Vasiliy Kalin. Ó sọ pé ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] ni ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ti wà lẹ́nu iṣẹ́, ó wá béèrè pé: “Ìgbà wo gan-an la di agbawèrèmẹ́sìn?” Ó fi kún un pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tíì yí pa dà, wọ́n máa ń gbọ́ràn sí àwọn aláṣẹ lẹ́nu, èèyàn àlàáfíà sì ni wọ́n lọ́jọ́kọ́jọ́. Ó sọ bó ṣe ká a lára tó pé àwọn èèyàn ń ṣe inúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Adájọ́ dá ẹjọ́ náà dúró títí di April 12, 2017, ìgbẹ́jọ́ máa bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́wàá àárọ̀.