Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

APRIL 6, 2017
RUSSIA

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Á Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lọ ní April 7

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Á Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lọ ní April 7

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ náà lónìí. Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. Wọ́n ní ó yẹ kí ilé ẹjọ́ fagi lé orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn àgbègbè tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin káàkiri orílẹ̀-èdè náà torí pé àwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké kan ti gbọ́ ẹjọ́ wọn láwọn ìlú kan, wọ́n sì sọ pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Adájọ́ wá bi aṣojú Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ bí ẹjọ́ tí wọ́n dá fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú mẹ́jọ ṣe kan Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn àti gbogbo àgbègbè márùn-dín-nírínwó [395] tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ ní Rọ́ṣíà. Adájọ́ tún béèrè ipa tó máa ní lórí ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba bá fagi lé orúkọ ẹ̀sìn wọn ní gbogbo ibi tí wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà. Léraléra ló tún béèrè ẹ̀rí tó fi hàn pé eléwu èèyàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ fáwọn aráàlú. Àwọn agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún bi àwọn aṣojú Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ láwọn ìbéèrè kan tó jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe pé Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ kàn fẹ́ fagi lé orúkọ ẹ̀sìn wọn láwọn àgbègbè tí wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ṣe ni wọ́n fẹ́ fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pátápátá.

Wọ́n ti dá ẹjọ́ náà dúró díẹ̀, wọ́n á máa gbọ́ ọ lọ ní April 7, 2017, ní aago mẹ́wàá àárọ̀.