Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

JULY 27, 2017
RUSSIA

Àwọn Aláṣẹ Rọ́ṣíà Fẹ́ Kéde Pé Ìwé “Agbawèrèmẹ́sìn” Ni Bíbélì

Àwọn Aláṣẹ Rọ́ṣíà Fẹ́ Kéde Pé Ìwé “Agbawèrèmẹ́sìn” Ni Bíbélì

ÌRÒYÌN LỌ́Ọ́LỌ́Ọ́: Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg ti sún ẹjọ́ yìí di August 9, 2017.

Tó bá di July 28, 2017, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg máa tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ tó dá lórí bí àwọn kan ṣe fẹ́ kí wọ́n kéde pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jáde lédè Rọ́ṣíà. Láti April 2016 ni wọ́n ti sún ẹjọ́ yìí síwájú, lẹ́yìn tí adájọ́ ti fọwọ́ sí ohun tí Agbẹjọ́rò Leningrad-Finlyandskiy Transport sọ, pé kí ilé ẹjọ́ yan àwọn “ọ̀jọ̀gbọ́n” tó máa ṣàyẹ̀wò Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kí wọ́n lè kéde pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ yìí falẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n parí àyẹ̀wò náà, wọ́n sì jábọ̀ fún ilé ẹjọ́ ní June 22, 2017. Báwọn Ẹlẹ́rìí sì ṣe retí pé ọ̀rọ̀ máa rí náà ló rí, àyẹ̀wò táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ọ̀hún ṣe fọwọ́ sí i pé kí ilé ẹjọ́ kéde pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì yìí. Wọ́n ní Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun “kì í ṣe Bíbélì.” Àmọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí ta ko ohun tí òfin sọ, ìyẹn òfin tó dá lórí Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn, èyí tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fòfin de àwọn ìwé mímọ́ bíi Bíbélì pé ó jẹ́ ìwé agbawèrèmẹ́sìn. Bákan náà, orí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ni àwọn tó pera wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n yìí gbé àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe kà. Wọn ò fara mọ́ bí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe túmọ̀ lẹ́tà Hébérù mẹ́rin * tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run sí “Jèhófà”, wọ́n sì fẹ̀sùn èké kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé àwọn ló yí ohun tó wà nínú Bíbélì pa dà kó lè bá ẹ̀kọ́ tiwọn mu.

^ ìpínrọ̀ 3 (יהוה) ni lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run, YHWH tàbí JHVH ló sì jẹ́ tá a bá túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] tó fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.