Ní October 18, 2016, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fọwọ́ sí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ kan dá pé àwọn fòfin de àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Orel torí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Ìkeje rèé nínú àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin tí àwọn ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fòfin dè. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe ni wọ́n ń ṣi òfin agbawèrèmẹ́sìn lò láti fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn aláṣẹ ìlú Orel ti ń gbìyànjú tẹ́lẹ̀ láti fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Orel, wọ́n hùmọ̀ irọ́ kan tí wọ́n fẹ́ lọ́ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀. Nígbà tí wọn ò rí i ṣe, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí ní May 2016 pé àjọ “agbawèrèmẹ́sìn” ni àjọ tí wọ́n forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Orel.

Ẹjọ́ yìí gbàfiyèsí gan-an torí pé lẹ́yìn tí Agbẹjọ́rò Àgbà ti kìlọ̀ fáwọn Ẹlẹ́rìí ní March 2016 pé òun máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn pa, ìlú Orel ni wọ́n tún ti kìlọ̀ fáwọn Ẹlẹ́rìí pé àwọn máa fòfin de ẹ̀sìn wọn, tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí.