Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

APRIL 13, 2016
RUSSIA

Àwọn Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Ò Dáwọ́ Dúró, Wọ́n Fẹ́ Kí Ìjọba Fòfin De Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àwọn Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Ò Dáwọ́ Dúró, Wọ́n Fẹ́ Kí Ìjọba Fòfin De Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Láwọn àgbègbè kan lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, àwọn aláṣẹ kan túbọ̀ ń fínná mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìrọwọ́rọsẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìjọsìn wọn, àmọ́ àwọn aláṣẹ ń fẹ̀sùn kàn wọ́n pé “agbawèrèmẹ́sìn” ni wọ́n.

  • Tyumen, ní Àgbègbè Tyumen. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ nílùú Tyumen. Àmọ́ agbẹjọ́rò kan fẹ̀sùn èké kan Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan pé ó ń “pín ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn.” Ọ̀rọ̀ náà dé ilé ẹjọ́, wọ́n sì sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà jẹ̀bi. Ni agbẹjọ́rò náà bá tún ń ṣọ̀nà bí ìjọba ṣe máa fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú yẹn. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà máa gbọ́ ẹjọ́ yìí ní April 14, 2016.

  • Ìlú Elista, ní Republic of Kalmykia. Ọ̀gá ọlọ́pàá nílùú Elista pàṣẹ pé kí àwọn ọlọ́pàá lọ tú inú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú yẹn. Wọ́n wá sọ pé àwọn rí ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan níbẹ̀ tó wà lára àwọn ohun tí ìjọba kà sí Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn. Bẹ́ẹ̀, àwọn ló lọ tọ́jú ìwé yẹn sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà kí wọ́n lè fi kó bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Òun ni agbẹjọ́rò Republic of Kalmykia wá gùn lé tó fi kọ̀wé pé kí ìjọba fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Elista. Ẹjọ́ yìí ṣì wà ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.

  • Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn aláṣẹ míì tún kọ̀wé pé kí ìjọba fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Stariy Oskol, Belgorod àtàwọn ibòmíì. Àwọn ẹjọ́ yìí náà ṣì wà ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.