Lẹ́yìn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà forúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní ọdún 1992, wọ́n kọ́kọ́ ń bá ìjọsìn wọn lọ láìsí wàhálà. Nígbà tó di ọdún 1999, àwọn Ẹlẹ́rìí tún forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ Òfin Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn àti Ẹ̀sìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè náà, tí wọ́n sì ń báṣẹ́ wọn lọ.

Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kojú ìṣòro tí kò jẹ́ kí wọ́n fi bẹ́ẹ̀ lómìnira ẹ̀sìn mọ́. Látọdún 2009, àwọn agbófinró ti ń ṣi òfin tó dá lórí Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn lò láti gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń mú kí àwọn èèyàn máa fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Ọ̀pọ̀ ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti fòfin dè pé wọ́n jẹ́ ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn, títí kan jw.org, ìkànnì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àìmọye ilé tí wọ́n ń gbé àti ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn ni àwọn ọlọ́pàá ti tú. Wọ́n ti fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí pé ọ̀daràn ni wọ́n, wọ́n sì ń ta ko ìjọba, bẹ́ẹ̀ sì rèé, torí pé wọ́n ń pàdé pọ̀ láti jọ́sìn Ọlọ́run ló bí gbogbo ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù àtàwọn iléeṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ míì kárí ayé ló ti dá sí ọ̀rọ̀ náà torí pé wọn ò fara mọ́ bí wọ́n ṣe ń fúngun mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tanú sí wọn yìí, àmọ́ ohun táwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti ṣe sọ́rọ̀ náà ò tó nǹkan. Àwọn agbófinró ò dẹwọ́ rárá, ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń dí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ iṣẹ́ wọn.