Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

FEBRUARY 27, 2017
RUSSIA

Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Lọ Yẹ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà Wò

Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Lọ Yẹ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà Wò

Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti lọ yẹ ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè náà wò, wọn ò sì mú un ní kékeré rárá. Agbẹjọ́rò Àgbà pàṣẹ fún Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ pé kí wọ́n sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí ní February 1, 2017 pé àwọn máa wá yẹ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn wò. February 8 sí February 27 ni wọ́n ṣètò láti lọ yẹ ibẹ̀ wò, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sì ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n rí i pé gbogbo àkọsílẹ̀ tó jẹ mọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà wà nílẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìwé tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìnáwó, bí wọ́n ṣe ṣètò iṣẹ́ wọn, bí wọ́n ṣe ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà sì kó àwọn ìwé ọ̀hún jọ, wọ́n sì kó o fún àwọn aláṣẹ ní February 15, 2017. Ojú ìwé àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì tí wọ́n kó fún wọn yìí lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́rin [73,000].

Ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Moscow dá lẹ́nu àìpẹ́ yìí, lórí ọ̀rọ̀ ohun tí Agbẹjọ́rò Àgbà sọ ní March 2016 pé àwọn máa ṣe sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí, ló bí àyẹ̀wò tí wọ́n ń ṣe yìí. Nígbà yẹn, ṣe ni Agbẹjọ́rò Àgbà halẹ̀ pé àwọn máa ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà pa lórí ẹ̀sùn pé iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀. Látìgbà yẹn, àwọn ilé ẹjọ́ míì ní Rọ́ṣíà ti sọ pé kí àwọn aláṣẹ fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ìlú kan lórí ẹ̀sùn pé “agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n,” bẹ́ẹ̀ sì rèé, kedere báyìí ló ṣe pé ṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ lọ́ ẹ̀sùn yìí mọ́ wọn lẹ́sẹ̀.

Pẹ̀lú àyẹ̀wò tí àwọn aláṣẹ ń ṣe yìí, ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò balẹ̀ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn pa láìpẹ́. Ohun táwọn aláṣẹ ń ṣe lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà yìí, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì dà bíi pé wọ́n ń dí wọn lọ́wọ́ ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe nírọwórọsẹ̀, ti fi hàn kedere pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ má fẹ ṣe ohun tí ìjọba àpapọ̀ sọ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni.