Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

RUSSIA

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Ní May 25, 2017, àwọn ọlọ́pàá tó dira ogun àtàwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé àárín ọ̀sẹ̀ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ nílùú Oryol, ní Rọ́ṣíà. Láti June 2016 làwọn aláṣẹ ti fagi lé orúkọ ẹ̀sìn táwọn Ẹlẹ́rìí fi sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Oryol lórí ẹ̀sùn pé iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n ń ṣe, àmọ́ ṣe làwọn aláṣẹ tún ń fẹ̀sùn kàn wọ́n báyìí pé ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọ wọn fi hàn pé wọ́n ṣì ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn tí wọ́n ti fẹ̀sùn rẹ̀ kàn wọ́n tẹ́lẹ̀.

Wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Dennis Christensen tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn alàgbà ìjọ Oryol torí ipa tó ń kó nínú ìjọ. Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Sovietsky pàṣẹ pé kí Ọ̀gbẹ́ni Christensen wà ní àtìmọ́lé títí di July 23, 2017, kí àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba lè ráyè kó ẹ̀rí jọ, kí wọ́n sì lè wá ẹlẹ́rìí tó máa ta ko Ọ̀gbẹ́ni Christensen nílé ẹjọ́. Àmọ́ ní May 29, 2017, Ọ̀gbẹ́ni Christensen kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ohun tí ilé ẹjọ́ sọ. Ilé ẹjọ́ sì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ní June 21, 2017, ṣùgbọ́n wọ́n fagi lé ìwé tó kọ, wọ́n sì pàṣẹ pé kó ṣì wà látìmọ́lé. Tí ilé ẹjọ́ bá wá sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Christensen jẹ̀bi ohun tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 282.2, apá 1, nínú Òfin Ìwà Ọ̀daràn, á jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà sí mẹ́wàá gbára nìyẹn.

Torí pé ọmọ ilẹ̀ Denmark ni Ọ̀gbẹ́ni Christensen, gbàrà táwọn agbófinró mú un la ti fi ọ̀rọ̀ náà tó Ọ́fíìsì Aṣojú Ìjọba Orílẹ̀-èdè Denmark tó wà nílùú Moscow létí, wọ́n sì rán àwọn aṣojú pé kí wọ́n lọ yọjú sí i lẹ́wọ̀n. Ìròyìn tá a gbọ́ ni pé àlàáfíà ló wà, wọn ò fìyà jẹ ẹ́.

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Dá Ẹjọ́ tí Kò Tọ́

Kó tó di pé àwọn aláṣẹ fagi lé orúkọ ẹ̀sìn táwọn Ẹlẹ́rìí fi sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Oryol, àwọn ọlọ́pàá lọ yẹ ilé ìjọsìn wọn wò, wọ́n wá sọ pé àwọn rí ìwé tó dá lórí Bíbélì níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kó gbogbo ìwé wọn kúrò nínú ilé ìjọsìn náà ṣáájú àkókò yẹn. Ṣe làwọn ọlọ́pàá lọ gbẹ̀yìn fi síbẹ̀ kó tó di pé wọ́n wá lọ́jọ́ náà, tí wọ́n sì sọ pé àwọn rí i. Ibi táwọn tó fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí wá yí i sí ni pé ṣe ni ìwé mélòó kan táwọn rí yìí jẹ́ ẹ̀rí pé “àwọn Ẹlẹ́rìí ń kó ìwé tí ìjọba fòfin dè pé ó jẹ́ ti agbawèrèmẹ́sìn pa mọ́ kí wọ́n lè máa pín in káàkiri.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà fagi lé e, wọ́n sì dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi.

Ní March 2017, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pe Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́jọ́, ẹjọ́ náà sì kan gbogbo ibi tó kù táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Rọ́ṣíà. Nígbà tó sì di April 20, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò gbà pé ó yẹ kí ìjọba máa pè wọ́n ní “agbawèrèmẹ́sìn” torí èèyàn àlàáfíà ni wọ́n lójoojúmọ́ ayé wọn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ẹjọ́ ti ìlú Oryol náà ló ṣẹlẹ̀, ẹ̀rí táwọn aláṣẹ sọ pé àwọn ní kì í ṣòótọ́. Ìwà tí kò bófin mu táwọn agbófinró ń hù àtàwọn ohun tí kò tọ́ táwọn tó pera wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n tí Ìjọba yàn ń sọ nípa ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn aláṣẹ fi ṣe ẹ̀rí láti ta kò wọ́n.

Wọ́n Ń Jà fún Òmìnira Ẹ̀sìn

Ní May 25, 2017 táwọn agbófinró ya lọ bá àwọn Ẹlẹ́rìí níbi tí wọ́n ti ń ṣèpàdé nílùú Oryol, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ kàn pàdé láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí pé èrò wọn jọra, kì í ṣe pé wọ́n ń ṣohun tí ìjọba dẹ́bi fún torí ohun tí wọ́n ń ṣe ò jẹ mọ́ ti àjọ tí wọ́n fòfin dè rárá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ohun tí wọ́n lè ṣe láti kàn sí àwọn aláṣẹ ní Rọ́ṣíà kí wọ́n lè ṣèrànwọ́, wọ́n sì ti fi ibi tí ọ̀rọ̀ dé báyìí tó àwọn àjọ tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé létí, pàápàá lórí ọ̀rọ̀ Dennis Christensen àti gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rọ́ṣíà.

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

 1. July 20, 2017

  Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Sovietsky sọ pé kí Dennis Christensen ṣì wà látìmọ́lé títí di November 23, 2017.

 2. June 21, 2017

  Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn pàṣẹ pé kí Dennis Christensen ṣì wà látìmọ́lé.

 3. May 26, 2017

  Ilé ẹjọ́ sọ pé kí wọ́n fi Dennis Christensen sí àtìmọ́lé fún oṣù méjì.

 4. May 25, 2017

  Àwọn agbófinró ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti ń jọ́sìn nílùú Oryol, wọ́n sì mú Dennis Christensen.