Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

NOVEMBER 29, 2016
RUSSIA

Kámẹ́rà Tú Àṣírí Àwọn Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Bí Wọ́n Ṣe Fẹ́ Mọ̀ọ́mọ̀ Lọ́ Ẹ̀sùn Irọ́ Mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́sẹ̀

Kámẹ́rà Tú Àṣírí Àwọn Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Bí Wọ́n Ṣe Fẹ́ Mọ̀ọ́mọ̀ Lọ́ Ẹ̀sùn Irọ́ Mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́sẹ̀

Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń wá gbogbo ọ̀nà láti lọ́ ẹ̀sùn irọ́ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́sẹ̀, kí ìjọba lè fòfin dè wọ́n pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Àtìgbà tí Agbẹjọ́rò Àgbà ti kọ lẹ́tà sí àwọn Ẹlẹ́rìí láti kìlọ̀ fún wọn pé àwọn máa ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa làwọn aláṣẹ ti túbọ̀ ń forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè lọ́ ẹ̀sùn mọ́ wọn lẹ́sẹ̀.

Orí ìkànnì www.jw-russia.org la ti mú fídíò yìí, a wá túmọ̀ ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Wàá rí bí àwọn agbófinró nílùú Nezlobnaya ṣe fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ lọ́ ẹ̀sùn irọ́ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́sẹ̀ lójúkojú.