Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

APRIL 19, 2017
RUSSIA

Ọjọ́ Karùn-ún: Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Gbé Àwọn Ẹ̀rí Yẹ̀ Wò Lórí Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ọjọ́ Karùn-ún: Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Gbé Àwọn Ẹ̀rí Yẹ̀ Wò Lórí Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Lónìí, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ìwé mẹ́tàlélógójì [43] yẹ̀ wò, èyí tí àwọn tọ́rọ̀ kàn kó wá sílé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀. Ilé ẹjọ́ tún gbà kí àwọn agbẹjọ́rò Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà fi àwọn ẹ̀rí tuntun kún èyí tó ti wà nílẹ̀, tó dá lórí bí àwọn aláṣẹ ṣe ń yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu nígbà tí wọ́n ń ṣèjọsìn lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Lóṣù March àti April 2017, àwọn agbófinró lọ síbi táwọn Ẹlẹ́rìí ti ń jọ́sìn, wọ́n da ibẹ̀ rú, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ àwọn tó wà níbẹ̀ pé àwọn máa fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n.

Bí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ṣe sọ, pé kí ìjọba fòfin de àwọn ibi márùn-dín-nírínwó [395] tí àwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Rọ́ṣíà, Ilé Ẹjọ́ gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn aṣojú nípa àwọn òfin àti ìlànà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé lórí iṣẹ́ wọn àti lórí ẹ̀sìn wọn. Nígbà tí adájọ́ gbé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ti dá tẹ́lẹ̀ yẹ̀ wò, lórí bí wọ́n ṣe fòfin de àwọn ibi mẹ́jọ táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀, àwọn agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹ̀sùn irọ́ ni àwọn aláṣẹ lọ́ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ nígbà yẹn, wọn ò sì tún tẹ̀ lé ìlànà tó yẹ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn agbẹjọ́rò Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ò mọ èyí tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ń ṣe gan-an, torí pé ọ̀rọ̀ wọn ti ń pé méjì báyìí. Lákọ̀ọ́kọ́, nígbà yẹn tí wọ́n fẹ́ fòfin de àwọn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ tẹnu mọ́ ọn pé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ohun tó ń lọ láwọn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Nígbà tí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà sì sọ pé àwọn fẹ́ wà níbi ìgbẹ́jọ́ yẹn, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ fàáké kọ́rí, wọ́n láwọn ò gbà. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ń sọ pé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì ló jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n ń ṣohun tó ta ko òfin láwọn ibi tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin àti ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” làwọn ìwé wọn.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ti lọ yẹ àwọn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin wò, wọ́n sì ti ròyìn ohun tí wọ́n rí níbẹ̀ fún Ilé Ẹjọ́. Síbẹ̀, nígbà tí adájọ́ bi Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ láwọn ìbéèrè kan, wọn ò rí ẹyọ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tọ́ka sí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti hùwà agbawèrèmẹ́sìn.

Ilé Ẹjọ́ ti sún ìgbẹ́jọ́ náà di April 20, 2017, ní aago méjì ọ̀sán.