Látọdún 1919 ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà ní àgbègbè tá a mọ̀ sí Palẹ́sínì báyìí. Wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ nílùú Ramallah lọ́dún 1920, wọ́n sì dá ìjọ kejì sílẹ̀ lọ́dún 1942, ní tòsí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Torí ogun tó jà ní Palẹ́sínì lọ́dún 1948, wọ́n pín ilẹ̀ náà sí méjì: Apá kan di orílẹ̀-èdè tuntun tá a mọ̀ sí Ísírẹ́lì, apá kejì sì bọ́ sórí ilẹ̀ Jọ́dánì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún (20) ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti ilẹ̀ Palẹ́sínì ò fi lè kàn sí ara wọn. Àmọ́ lẹ́yìn Ogun Ọlọ́jọ́ Mẹ́fà tó jà lọ́dún 1967, àwọn Ẹlẹ́rìí lórílẹ̀-èdè méjèèjì tún láǹfààní láti bá ara wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì tún pa dà lómìnira láti máa pé jọ, kí wọ́n sì máa báṣẹ́ wọn lọ ní àgbègbè West Bank.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Palẹ́sínì ti gbìyànjú láti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn aláṣẹ ò fọwọ́ sí i. Àwọn Ẹlẹ́rìí lè pé jọ láti jọ́sìn, wọ́n sì lè bá àwọn aládùúgbò wọn sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́, àmọ́ torí ìjọba ò gbà kí wọ́n forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí wọ́n ní dù wọ́n. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń sapá kí wọ́n lè ní àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kan, kí wọ́n sì tún láwọn ẹ̀tọ́ kan lábẹ́ òfin.