Àárín ọdún 1870 sí 1879 ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìgbà yẹn ni Charles Taze Russell àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kóra jọ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láwọn ọdún mélòó kan tó tẹ̀ lé e, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé jáde, wọ́n dá iléeṣẹ́ kan sílẹ̀, èyí tá a wá mọ̀ sí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, wọ́n sì ṣí oríléeṣẹ́ wọn àkọ́kọ́ sí Allegheny, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Àmọ́ láàárín ọdún 1900 sí 1940, àwọn aṣáájú ìsìn kan tẹ́nu wọn tólẹ̀ àtàwọn aláṣẹ táwọn èèyàn kan ti kó sí lórí gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gidigidi. Pàápàá láàárín ọdún 1930 sí 1949, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fojú ba ilé ẹjọ́. Àwọn ọlọ́pàá mú àwọn Ẹlẹ́rìí torí pé wọ́n ń wàásù, àwọn aláṣẹ iléèwé káàkiri orílẹ̀-èdè náà lé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò níléèwé torí pé wọn ò kí àsíá, bẹ́ẹ̀ sì làwọn ilé ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ rán ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Àmọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre nínú àwọn ẹjọ́ yìí.

Títí di báyìí, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti dá àwọn Ẹlẹ́rìí láre nínú àádọ́ta [50] ẹjọ́ tó kàn wọ́n. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti dá àwọn Ẹlẹ́rìí láre lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ tí aláìsàn ní, ẹ̀tọ́ òbí láti bójú tó ọmọ, ọ̀rọ̀ ilé kíkọ́, ẹ̀tanú táwọn èèyàn ń ṣe sí wọn tí wọ́n bá ń wáṣẹ́ àti lórí ọ̀rọ̀ gbígba àwọn tí kì í ṣe ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà láyè láti wọlé sí orílẹ̀-èdè náà. Bí ilé ẹjọ́ ṣe dá wọn láre yìí ti mú kí ìjọba ṣàtúnṣe sáwọn òfin ilẹ̀ náà, ó ti fún àwọn aráàlú lómìnira ọ̀rọ̀ sísọ, òmìnira láti gbé ìròyìn jáde, láti kóra jọ àti òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn ẹni, pabanbarì ẹ̀ ni pé ó ti nípa rere lórí àwọn ilé ẹjọ́ gíga tó wà kárí ayé.