Ìjọba orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti tó wọ iṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ológun. Ìjọba ò gbà pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ ọ́, wọn ò sì ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú láti fi rọ́pò rẹ̀. Torí náà, wọ́n ń rán àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lọ sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn wọn pé kò tọ́ kéèyàn máa gbé ohun ìjá láti bá ẹnì kejì rẹ̀ jà.

Wọn Ò Gbà Kí Wọ́n Ṣe Iṣẹ́ Àṣesìnlú Dípò Iṣẹ́ Ológun

Ní January 29, 2014, ẹ̀ka iṣẹ́ ológun nílùú Askeran, ìyẹn Askeran City Military Commissariat ránṣẹ́ pé Artur Avanesyan, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pé kó wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ológun. Lọ́jọ́ kejì, Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan kọ̀wé sí ẹ̀ka iṣẹ́ ológun tó jẹ́ ti ìjọba orílẹ̀-èdè náà, ìyẹn Nagorno-Karabakh Military Commissariat. Ó ní kí wọ́n jẹ́ kóun ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun. Agbẹjọ́rò rẹ̀ ò sì fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀, ó lọ kàn sí àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh àti Àméníà kí wọ́n lè jẹ́ kí Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan ṣiṣẹ́ àṣesìnlú ní Àméníà, ó sì ti bá ọ̀rọ̀ náà débì kan.

Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan lérò pé ọ̀rọ̀ náà á yọrí síbi tó dáa, ló bá kó lọ sí orílẹ̀-èdè Àméníà, ó sì kọ̀wé sí ẹ̀ka iṣẹ́ ológun tó ń jẹ́ Masis Military Commissariat lórílẹ̀-èdè náà ní February 13, 2014 pé kí wọ́n jẹ́ kóun ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú. Èrò rẹ̀ ni pé ìjọba máa ní kóun lọ rí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí iṣẹ́ àṣesìnlú, àmọ́ ṣe ni wọ́n ránṣẹ́ sí i ní July 14, 2014 pé kó lọ sí àgọ ọlọ́pàá tó wà nílùú Yerevan lọ́jọ́ yẹn. Nígbà tó débẹ̀, àwọn ọlọ́pàá láti orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh ló rí, àṣé wọ́n ti ń dúró dè é níbẹ̀. Ni wọ́n bá mú un pa dà sí Nagorno-Karabakh. Lọ́jọ́ kejì, wọ́n tì í mọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọ́n wá mú un lọ sí ilé ẹjọ́ tó máa ń kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ tí ọ̀rọ̀ kan bá wáyé lórílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh.

Ibẹ̀ ló ti mò pé ilé ẹjọ́ yìí ti ní kí àwọn agbófinró wá mú òun tẹ́lẹ̀ ní oṣù mẹ́rin sẹ́yìn, kí wọ́n sì ti òun mọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ òun. Ilé ẹjọ́ náà ṣì gùn lé ohun tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n sì fi Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan sẹ́wọ̀n. Ó gbìyànjú títí kí wọ́n má bàa fi òun sí àtìmọ́lé láìtíì dúró rojọ́, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí.

Ní September 30, 2014, ilé ẹjọ́ kéde pé Ògbẹ́ni Avanesyan jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì àtààbọ̀. Ilé Ẹjọ́ Kọ̀tẹ́milọ́rùn náà sọ pé àwọn fọwọ́ sí i. Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan wá kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Nagorno-Karabakh, àmọ́ ní December 25, 2014, Ilé Ẹjọ́ Gíga yìí náà sọ pé àwọn fara mọ́ ọn pé ó jẹ̀bi.

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh ṣì ń fi àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí pé wọn ò fẹ́ ṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn ti wọ́n fi Bíbélì kọ́. Àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ta ko ohun tí ìjọba àpapọ̀ fọwọ́ sí kárí ayé, ìyẹn bí ìjọba ṣe fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun.

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

 1. December 25, 2014

  Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Nagorno-Karabakh sọ pé Artur Avanesyan jẹ̀bi lóòótọ́.

 2. September 30, 2014

  Ilé ẹjọ́ tó wà nílùú Martakert, tó máa ń kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ tí ọ̀rọ̀ kan bá wáyé lórílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh, sọ pé Artur Avanesyan jẹ̀bi, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì àtààbọ̀.

 3. July 14, 2014

  Wọ́n mú Artur Avanesyan ní orílẹ̀-èdè Àméníà, wọ́n sì dá a pa dà sí Nagorno-Karabakh, wọ́n wá fi sí àtìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀.

 4. December 30, 2011

  Wọ́n rán Karen Harutyunyan, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì àtààbọ̀ torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.

 5. February 16, 2005

  Wọ́n rán Areg Avanesyan, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.

 6. June 12-13, 2001

  Wọ́n rán àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta lọ sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́fà sí ọdún kan torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́ṣẹ́ ológun.