Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

SEPTEMBER 12, 2016
NAGORNO-KARABAKH

Wọ́n Dá Artur Avanesyan Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n Nígbà Tí Ìjọba Dá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Kan Sílẹ̀

Wọ́n Dá Artur Avanesyan Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n Nígbà Tí Ìjọba Dá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Kan Sílẹ̀

Ní September 6, 2016, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh dá Artur Avanesyan, tó jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Shushi torí pé ìjọba ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan ti lo ọdún méjì àti oṣù méjì nínú ẹ̀wọ̀n ọdún méjì ààbọ̀ tí wọ́n rán an lọ torí pé ó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun. Bẹ́ẹ̀, ó ní kí ìjọba jẹ́ kóun ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò, àmọ́ wọn ò fọwọ́ sí i. Inú ọ̀dọ́kùnrin yìí dùn gan-an pé òun ti pa dà sílé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí òun báyìí.

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn pé wọ́n ti dá Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Wọ́n ń retí pé kí àwọn aláṣẹ fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é, kí wọ́n sì jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó wà ní Nagorno-Karabakh máa ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò kí wọ́n fi dandan mú wọn wọṣẹ́ ológun.