Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Nagorno-Karabakh

AUGUST 10, 2016

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh Rán Ẹni tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun Lọ Sẹ́wọ̀n Láìtọ́

Artur Avanesyan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì ààbọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Shushi lórílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh. Bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ́kùnrin yìí sọ pé òun ṣe tán láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun.