Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MARCH 1, 2016
KYRGYZSTAN

Ṣé Àwọn tí Ọlọ́pàá Lù Nílùkulù Nílùú Osh Máa Jìyà Yìí Gbé Ni?

Ṣé Àwọn tí Ọlọ́pàá Lù Nílùkulù Nílùú Osh Máa Jìyà Yìí Gbé Ni?

Ẹ̀ẹ̀kẹta rèé tí Agbẹjọ́rò Àgbà orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ti ní kí Agbẹjọ́rò Ìjọba nílùú Osh fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn ọlọ́pàá mẹ́wàá, kó sì ṣèwádìí nípa wọn. Ní August 2015, ṣe làwọn ọlọ́pàá ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé, wọ́n sì lu àwọn kan lára àwọn tó wà nípàdé náà nílùkulù. Ó ṣe kedere pé àwọn ọlọ́pàá yìí kọjá àyè wọn, àmọ́ Agbẹjọ́rò Ìjọba nílùú Osh ò gbà láti pe àwọn ọlọ́pàá náà lẹ́jọ́.

Àwọn Ọlọ́pàá Ya Wọ Ilé Ìjọsìn, Wọ́n sì Ṣe Àwọn Èèyàn Ṣúkaṣùka

Láàárọ̀ ọjọ́ Sunday, August 9, 2015, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ìsìn nílé oúnjẹ kan tí wọ́n yá, àwọn tó lé ní ogójì (40) ló sì ń jọ́sìn níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ní ìrọwọ́rọsẹ̀. Ni mẹ́wàá nínú àwọn ọlọ́pàá ìlú Osh láti Department 10 * bá ya wọ ibẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́pàá náà kígbe mọ́ Nurlan Usupbaev, tó ń darí ìpàdé náà pé kó dáwọ́ ohun tó ń ṣe dúró torí kò “bófin mu.” Ṣe làwọn ọlọ́pàá náà ń halẹ̀ ṣáá pé àwọn máa yìnbọn pa gbogbo àwọn tó wá sípàdé yẹn. Àwọn ọlọ́pàá náà ká Tynchtyk Olzhobayev, tí òun náà wá sípàdé yẹn bó ṣe ń gbìyànjú láti fídíò bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn èèyàn ṣúkaṣùka, ni wọ́n bá mú un wọnú yàrá kan, wọ́n sì lù ú bí ẹni máa kú.

Àwọn ọlọ́pàá náà mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n lu mẹ́fà lára wọn nílùkulù, wọ́n fún Ọ̀gbẹ́ni Usupbaev àtàwọn mẹ́ta tó kù lọ́rùn. Wọ́n pa dà fi àwọn ọkùnrin náà sílẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, àwọn tó sì fara pa yánnayànna nínú wọn lọ sílé ìwòsàn lọ gbàtọ́jú.

Lọ́jọ́ kẹta, August 11, ọlọ́pàá méjì, Kozhobek Kozubayev àti Nurbek Sherikbayev mú Ọ̀gbẹ́ni Usupbaev pé ó ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu. Àwọn ọlọ́pàá méjèèjì yìí ló kó àwọn yòókù ya wọnú ilé ìpàdé lọ́jọ́ méjì sẹ́yìn, tó sì ní kí wọ́n na àwọn tó wà. Ilé Ẹjọ́ Ìlú Osh máa gbọ́ ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni Usupbaev ní August 20 àti 21.

Àwọn Ilé Ẹjọ́ Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láre Pé Wọ́n Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Jọ́sìn

Nílé ẹjọ́, aṣojú Department 10 sọ pé ìpàdé ẹ̀sìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní August 9 ò bófin mu torí pé wọn ò forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ nílùú Osh. Wọ́n tún fẹ̀sùn kan àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n mú àwọn ọmọ wọn lọ sípàdé, ìyẹn sì ta ko òfin tí orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ṣe nípa ẹ̀sìn, tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fa àwọn ọmọdé wọnú ẹ̀sìn.

Ní August 21, adájọ́ Ilé Ẹjọ́ ìlú Osh rí i pé Ọ̀gbẹ́ni Usupbaev ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu. Ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n fagi lé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án torí kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu tàbí pé ó “fa” àwọn ọmọdé wọnú ẹ̀sìn.

Ni Agbẹjọ́rò Ìjọba nílùú Osh bá kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ìpínlẹ̀ nílùú Osh, ó ní òun ò fọwọ́ sí i pé kí wọ́n dá Ọ̀gbẹ́ni Usupbaev sílẹ̀. Ilé ẹjọ́ náà fagi lé ìwé tí agbẹjọ́rò náà kọ, ó sì kọ́wọ́ ti ìpinnu tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ ṣe pé kí wọ́n dá Ọ̀gbẹ́ni Usupbaev sílẹ̀. Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ náà tẹnu mọ́ ọn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan. Ilé ẹjọ́ náà tún kíyè sí i pé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti fagi lé òfin orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan tó sọ pé kí ẹ̀sìn máa forúkọ sílẹ̀ ní ìlú kọ̀ọ̀kan. * Àmọ́ ní báyìí, agbẹjọ́rò náà tún ti kọ̀wé pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, wọ́n á sì gbọ́ ẹjọ́ náà ní March 2, 2016.

Wọ́n Pàṣẹ Pé Kí Agbẹjọ́rò Ìjọba Pe Àwọn Ọlọ́pàá Náà Lẹ́jọ́

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni Usupbaev ṣì wà nílé ẹjọ́, òun àtàwọn tí wọ́n lù nílùkulù ní August 9 tí wọ́n ya wọ ibi tí wọ́n ti ń ṣèpàdé kọ̀wé sí Agbẹjọ́rò Ìjọba nílùú Osh. Wọ́n ní kí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn ọlọ́pàá mẹ́wàá tó lu àwọn nílùkulù. Àwọn èèyàn yìí ò yéé kọ̀wé. Ẹ̀ẹ̀mẹta ni Agbẹjọ́rò Ìjọba nílùú Osh kọ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n sọ, gbogbo ìgbà tó bá sì ti kọ̀ làwọn náà ń kọ̀wé sí Agbẹjọ́rò Àgbà. Ẹ̀ẹ̀mejì ni Agbẹjọ́rò Àgbà kọ̀wé sí Agbẹjọ́rò Ìjọba pé ó gbọ́dọ̀ ri i pé ó ṣe ohun tí wọ́n sọ. Àmọ́ lẹ́ẹ̀kẹta tí àwọn tí wọ́n lù kọ̀wé sí Agbẹjọ́rò Àgbà, dípò kó wá nǹkan ṣe sí i, ṣe ló dá ìwé náà pa dà sọ́dọ̀ Agbẹjọ́rò Ìjọba pé kó gbé ìgbésẹ̀. January 21, 2016 ni Agbẹjọ́rò Àgbà dá ìwé náà pa dà, ṣe àwọn tí wọ́n lù nílùkulù á wá jìyà yìí gbé?

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan dùn pé ìjọba ti forúkọ ẹ̀sìn àwọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì ń dúpẹ́ pé ilé ẹjọ́ ìlú Osh gbèjà àwọn lórí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Wọ́n mọrírì àwọn adájọ́ tí wọ́n tẹ̀ lé òfin àtohun tí ìjọba fọwọ́ sí lórí ọ̀ràn òmìnira ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́, tí wọ́n sì fìgboyà dájọ́ òdodo kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Àmọ́ inú wọn ò dùn pé ìjọba ò tíì gbé ìgbésẹ̀ láti fìyà tó tọ́ jẹ àwọn ọlọ́pàá tó lu àwọn èèyàn wọn nílùkulù. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bẹ Agbẹjọ́rò Àgbà pé kó gbé ìgbésẹ̀ tó tọ́, kó sì pe àwọn tó hùwà tó lè gbẹ̀mí ẹni yìí lẹ́jọ́.

^ ìpínrọ̀ 4 Ẹ̀ka Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ohun Tó Ń Lọ Lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ni Department 10.

^ ìpínrọ̀ 10 Ìpinnu tí wọ́n ṣe ní September 4, 2014. Wo Àpilẹ̀kọ náà “Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan Fọwọ́ sí I Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lómìnira Láti Ṣe Ẹ̀sìn Wọn.”