Mánigbàgbé ni September 4, 2014 jẹ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan, torí ọjọ́ náà ni ìjọba fọwọ́ sí i pé wọ́n lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Lọ́jọ́ yẹn, Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ kéde pé àwọn ọ̀rọ̀ kan nínu Òfin Ẹ̀sìn ti ọdún 2008 * ta ko òfin orílẹ̀-èdè. Ìpinnu tí wọ́n ṣe yẹn fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn wọn, kí ẹnì kankan má sì yọ wọ́n lẹ́nu láwọn àgbègbè tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan, tí wọ́n ti ń fòfin de ẹ̀sìn wọn láti ọdún mẹ́rin sẹ́yìn.

Ọdún 1998 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan, wọn kì í sì í sábà yọ wọ́n lẹ́nu ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ láti ìgbà tí wọ́n ti fi Òfin Ẹ̀sìn ti ọdún 2008 lọ́lẹ̀ làwọn ọlọ́pàá ti ń yọ wọ́n lẹ́nu, àìmọye ìgbà ni wọ́n ti lọ ya bo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé láwọn àgbègbè tó wà ní gúúsù Kyrgyzstan nígbà tí wọ́n ń ṣèpàdé lọ́wọ́, wọn ò yéé sọ pé ohun táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe láwọn àgbègbè yìí “ò bófin mu” torí pé wọn ò forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ láwọn àgbègbè náà. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀sìn lábẹ́ ìdarí Ìjọba Ìpínlẹ̀ ṣi àwọn apá kan lára Òfin Ẹ̀sìn ti ọdún 2008 lò kí wọ́n lè dínà mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí wọ́n má bàa rí orúkọ ẹ̀sìn wọn fi sílẹ̀ lábẹ́ òfin láwọn àgbègbè yìí. Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe ní September 4 yìí fẹ̀yìn gbogbo wọn balẹ̀.

Òfin Gbé Ìgbésẹ̀

Òfin Ẹ̀sìn ti ọdún 2008 fòfin de “ìgbòkègbodò ẹ̀sìn” láì forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin (Àpilẹ̀kọ 8(2)). Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀sìn lábẹ́ ìdarí Ìjọba Ìpínlẹ̀ wá ń tibẹ̀ yẹn fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ìlú tí wọn ò ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan. Òfin yìí kan náà tún sọ pé kí ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan mú orúkọ igba (200) èèyàn tí òfin fọwọ́ sí, tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn náà wá fún ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìlú, kí ìgbìmọ̀ náà sì fọwọ́ sí i (Àpilẹ̀kọ 10(2)) kí ẹ̀sìn náà tó lè lọ forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀sìn lábẹ́ ìdarí Ìjọba Ìpínlẹ̀. Òfin yìí há àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, torí Ìgbìmọ̀ yìí jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kí wọ́n tó lè máa ṣe ẹ̀sìn wọn láìsí ìyọlẹ́nu, wọ́n gbọ́dọ̀ forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ ní ìlú kọ̀ọ̀kan, àmọ́ wọn ò rí i ṣe torí àwọn ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìlú ò fọwọ́ sí orúkọ àwọn èèyàn tí wọ́n mú wá. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀sìn lábẹ́ ìdarí Ìjọba Ìpínlẹ̀ àtàwọn ìgbìmọ̀ ti ìlú wá ń fìyẹn halẹ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí pé wọn ò lè forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Wọ́n ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára gan-an, ìyẹn wá mú kí wọ́n kọ̀wé sí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin pé ohun tí òfin ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ti pọ̀ jù.

Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ṣèpinnu, wọ́n sọ pé “àparò kan ò ga jùkan lọ, òfin ò fojú kéré ẹ̀sìn kankan, wọn ò sì gbọdọ̀ fojú kéré tàbí ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni tàbí ẹ̀sìn èyíkéyìí.” Ilé Ẹjọ́ náà kéde pé Àpilẹ̀kọ 10(2), tó sọ pé kí ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan mú orúkọ àwọn tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn náà wá fún ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìlú, kí ìgbìmọ̀ náà sì fọwọ́ sí i, ta ko òfin orílẹ̀-èdè. Ilé Ẹjọ́ náà tún sọ pé wọ́n ti ṣi Àpilẹ̀kọ 8(2) nínú òfin náà lóye. Ilé Ẹjọ́ náà sọ pé òmìnira tí ẹ̀sìn kan ní gba ẹ̀sìn náà láyè láti ṣe ẹ̀sìn wọn fàlàlà níbikíbi lórílẹ̀-èdè náà tí wọ́n bá kọ sínú ìwé tí wọ́n fi forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba. Nínú ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan lọ́dún 1998, wọ́n ti kọ ọ́ síbẹ̀ pé kárí orílẹ̀-èdè náà làwọn ti fẹ́ máa ṣe ẹ̀sìn àwọn. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn ní gbogbo àgbègbè Kyrgyzstan láìsí ẹni tó máa yọ wọ́n lẹ́nu.

Ìpinnu Yìí Mú Ìtura Bá Àwọn tí Wọ́n Ń Ṣe Ojúṣàájú sí

Ìròyìn ayọ̀ ni ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ ṣe ní September 4 yìí jẹ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan, pàápàá fún Oksana Koriakina àti ìyá rẹ̀, Nadezhda Sergienko, tí wọ́n ń gbé nílùú Osh. Wọ́n fòfin dè wọ́n pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé láti March 2013 torí wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n hùwà ọ̀daràn nígbà tí wọ́n ń bá àwọn kan sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Oksana àti Nadezhda ò mọwọ́ mẹsẹ̀, wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n rẹ́ àwọn ìyá àgbàlagbà mẹ́ta kan jẹ torí wọ́n dọ́gbọ́n gbowó lọ́wọ́ wọn.

September 2014 ni wọ́n gbọ́ ẹjọ́ wọn ní Ilé Ẹjọ́ ìlú Osh, àmọ́ ní October 7, 2014, ilé ẹjọ́ kéde pé àwọn obìnrin méjèèjì ò jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n, wọ́n sì kéde pé kí wọ́n sanwó gbà-máà-bínú fún wọn torí wọ́n fẹ̀sùn tí kò tọ́ kàn wọ́n, wọ́n tì wọ́n mọ́lé, wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n jáde. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé ìdí tí wọ́n ṣe jìyà lọ́nà àìtọ́ ni pé ìjọba ò ka ẹ̀sìn wọn sí, wọ́n sì kórìíra wọn, àti pé wọ́n ti gbà pé òfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Osh torí pé wọn ò forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú yẹn. Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ṣe ní September 4 ni Oksana àti Nadezhda fi gbèjà ara wọn níparí ọ̀rọ̀ wọn, èyí tó gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè láti ṣe ẹ̀sìn wọn nílùú Osh àti jákèjádò orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan.

Oksana Koriakina àti Nadezhda Sergienko

Wọ́n Ti Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lẹ́yìn

Orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ti fọwọ́ sí àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè gbé kalẹ̀, wọ́n ti ṣèlérí pé àwọn ò ní tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú, àwọn á sì jẹ́ káwọn èèyàn orílẹ̀-èdè àwọn lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, láti pé jọ, kí wọ́n sì lómìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ṣe yìí ti gbèjà ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn èèyàn, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lómìnira láti ṣe ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ wọn lábẹ́ òfin, ìyẹn ti wá jẹ́ káwọn èèyàn lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] tó ń gbé ni Kyrgyzstan mọyì òmìnira tí wọ́n fún wọn láti ṣe ẹ̀sìn wọn, wọ́n sì mọrírì àwọn iléeṣẹ́ Ìjọba tó gbèjà wọn, tó sì jẹ́ kí gbogbo mùtúmùwà lómìnira láti ṣe ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ wọn lábẹ́ òfin.

^ ìpínrọ̀ 2 Àpèjá orúkọ òfin yìí ni “Òfin tí Orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan Ṣe Lórí Ọ̀rọ̀ Òmìnira Ẹ̀sìn Lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan.”