Àtọdún 1956 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan, wọ́n sì forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1998. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbà kan wà tí wọn ò jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìjọba ti túbọ̀ ń gbèjà wọn kí ẹnikẹ́ni má bàa fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n.

Ní November 2013, Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fohùn ṣọ̀kan pé òfin tí ìjọba orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ṣe lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ àṣesìnlú ta ko òfin ilẹ̀ náà, wọ́n sì pàṣẹ pé kí ìjọba tún un ṣe. Àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Kyrgyzstan tẹ̀ lé ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ṣe. Torí náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2014, wọn ò pe àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lẹ́jọ́ mọ́ torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Nígbà tó di June 29, 2015, ìjọba orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ṣàtúnṣe sí òfin iṣẹ́ ológun kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe é lè láǹfààní láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun.

Ní September 2014, Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ kéde pé àwọn apá ibì kan nínú òfin tí ìjọba ṣe lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn lọ́dún 2008 kò bófin ilẹ̀ náà mu. Bí wọ́n ṣe dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre, tí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lómìnira ẹ̀sìn nìyẹn. Àmọ́ Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn ò tẹ̀ lé ohun tí Ilé Ẹjọ́ náà sọ, wọ́n sì kọ̀ láti forúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ láwọn ìlú kan ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè náà. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ti mú káwọn aláṣẹ kan máa wò ó pé iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ò bófin mu. Àmọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí bá ti lọ rí àwọn aláṣẹ kí wọ́n lè ṣàlàyé ara wọn, wọ́n sábà máa ń jẹ́ kí wọ́n pàdé pọ̀ láti jọ́sìn, kí wọ́n sì sọ ohun tí wọ́n bá gbà gbọ́ fáwọn aládùúgbò wọn láìsí ìdíwọ́ kankan. Àwọn Ẹlẹ́rìí ń retí pé kí ìjọba tẹ̀ lé ohun tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin sọ délẹ̀délẹ̀, kí wọ́n sì bá wọn forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ láwọn ìlú kan ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan.