Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan máa tó gbọ́ ẹjọ́ méjì tó ní ín ṣe pẹ̀lú òmìnira ẹ̀sìn, ìbákẹ́gbẹ́ àti ọ̀rọ̀ sísọ.

  • February 15, 2016. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn torí pé Ìgbìmọ̀ Abẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀sìn kọ̀ láti forúkọ àjọ mẹ́rin sílẹ̀ lábẹ́ ẹ̀sìn náà. Bí wọ́n ṣe kọ̀ láti forúkọ wa sílẹ̀ yìí ta ko òfin tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin gbé kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ní September 4, 2014.

  • February 24, 2016. Agbẹjọ́rò Ìjọba nílùú Osh pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn torí pé ilé ẹjọ́ sọ pé Oksana Koriakina àti ìyá rẹ̀, Nadezhda Sergienko ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Ó ya àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu pé Agbẹjọ́rò Àgbà náà gbè sẹ́yìn Agbẹjọ́rò Ìjọba, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹjọ́ táwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké dá fi hàn kedere pé ìjọba fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn yìí dù wọ́n.