Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JANUARY 26, 2017
KAZAKHSTAN

Àwọn Aláṣẹ ní Kazakhstan Dẹ Pańpẹ́ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan, Wọ́n Lọ́ Ẹ̀sùn Mọ́ Ọn Lẹ́sẹ̀, Wọ́n sì Fi Sẹ́wọ̀n

Àwọn Aláṣẹ ní Kazakhstan Dẹ Pańpẹ́ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan, Wọ́n Lọ́ Ẹ̀sùn Mọ́ Ọn Lẹ́sẹ̀, Wọ́n sì Fi Sẹ́wọ̀n

Ní January 18, 2017, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ààbò lórílẹ̀-èdè Kazakhstan mú Ọ̀gbẹ́ni Teymur Akhmedov, wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n torí pé ó ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn míì. Ní May sí June ọdún 2016, àwọn ọkùnrin méje pe Teymur wá sí ilé kan tí wọ́n yá, wọ́n láwọn nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n tún wá sílé Teymur lápá ìparí ọdún yẹn. Teymur ò mọ̀ pé ọgbọ́nkọ́gbọ́n làwọn aráabí ń ta, àṣé àwọn méje tó rò pé òun ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ń fi kámẹ́rà ká gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀.

Àwọn aláṣẹ wá fẹ̀sùn kan Teymur torí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tó ń bá àwọn ọkùnrin yìí sọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀rọ̀ àlàáfíà ni. Wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó ń “dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn,” ó sì ń “gbé [ẹ̀sìn] kan ga ju àwọn yòókù lọ.” Wọ́n ti fi sí àtìmọ́lé olóṣù méjì títí dìgbà tí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Tí ilé ẹjọ́ bá sọ pé ó jẹ̀bi, ó máa fẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá gbára.

Ẹni ọgọ́ta [60] ọdún ni Teymur, ó ti níyàwó, ó sì ní àìsàn kan tó le tó ń bá fínra. Ó ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn torí bí wọ́n ṣe fi sí àtìmọ́lé yìí, àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ sì ń retí kí ilé ẹjọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà ní ọ̀sẹ̀ January 23, 2017.