Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ọgbẹ́ni Teymur Akhmedov rèé kí wọ́n tó fi sẹ́wọ̀n

OCTOBER 13, 2017
KAZAKHSTAN

Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan Jẹ̀bi fún Bó Ṣe Fi Teymur Akhmedov sí Àtìmọ́lé Lọ́nà Àìtọ́

Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan Jẹ̀bi fún Bó Ṣe Fi Teymur Akhmedov sí Àtìmọ́lé Lọ́nà Àìtọ́

Ẹgbẹ́ kan tó wà lábẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè tó máa ń rí sí ẹjọ́ àwọn tí wọ́n fi sí àtìmọ́lè lọ́nà àìtọ́, ìyẹn WGAD sọ pé ìjọba ilẹ̀ Kazakhstan jẹ̀bi fún bó ṣe fi Teymur Akhmedov sí àtìmọ́lé lọ́nà àìtọ́. * Nínú ìròyìn tó jáde ní October 2, 2017, ẹgbẹ́ WGAD là á mọ́lẹ̀ pé kò bófin mu rárá bí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ṣe fi Ọ̀gbẹni Akhmedov sí àtìmọ́lé lati January 18, 2017, torí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, tí kò sì bá ẹnikẹ́ni fa wàhálà kankan.

Ohun tí Ẹgbẹ́ WGAD Fẹnu Kò Lé Lórí

Ìwádìí tí ẹgbẹ́ WGAD ṣe ti jẹ́ kí wọ́n rí i kedere pé bí wọ́n ṣe fi Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sẹ́wọ̀n kò bófin mu rárá. Wọ́n sọ pé ńṣe ni ìjọba fi ẹ̀tọ́ Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov dù ú láti ṣe ìjọsìn tó wù ú àti láti sọ ohun tó gbàgbọ́. Wọ́n tún jẹ̀bi fún bí wọ́n ṣe gbè sápá kan nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà bójú tó ẹjọ́ rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ ẹ́ torí pé ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ẹgbẹ́ WGAD wá sọ pé àwọn ò fọwọ́ sí bí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ṣe fi Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sí àtìmọ́lé rárá. Wọ́n wá sọ pé kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ àti pé Ìgbìmọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti bẹnu àtẹ́ lu ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan pé “ńṣe ni wọ́n ń fẹ ọ̀rọ̀ agbawèrèmẹ́sìn lójú ju bó ṣe yẹ lọ . . . àti pé ńṣe ni wọ́n ń fi òfin tí wọ́n gbé kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ni àwọn èèyàn lára, wọ́n sì ń fi òmìnira wọn dù wọ́n láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, láti sọ̀rọ̀ àti láti pé jọ.” Ẹgbẹ́ WGAD sọ pé òfin tí wọ́n ṣe yìí “kò ní jẹ́ káwọn èèyàn gbádùn ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n” àti pé “ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov jẹ́ ẹ̀rí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ń fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn dù wọ́n.”

Àmọ́ léraléra ni ẹgbẹ́ WGAD ṣàlàyé pé àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn tí Ọ̀gbẹni Akhmedov ń ṣe “kò mú wàhálà lọ́wọ́ rárá” àti pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tó ń bá àwọn èèyàn sọ kò mú kí wọ́n máa hùwà jàgídíjàgan tàbí kí wọ́n kórìíra àwọn ẹlẹ́sìn míì. Ẹgbẹ́ náà tún sọ pé ìjọba “kò rí ẹ̀rí kankan tọ́ka sí láti fi hàn pé Ọ̀gbẹni Akhmedov ń dáná ìjàngbọ̀n sílẹ̀.” Bákan náà, ìjọba “kò ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi sọ pé èèyànkéèyàn ni Ọ̀gbẹni Akhmedov torí pé ó ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn míì, tó sì ń sọ̀rọ̀ ẹ̀sìn láìbá ẹnikẹ́ni fa wàhálà.” Wọ́n tún sọ pé “ẹgbẹ́ WGAD mọ̀ dáadáa pé Ọ̀gbẹni Akhmedov kò rú òfin kankan, àmọ́ ó kàn ń lo òmìnira tàbí ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù ú bó ṣe wà nínú àpilẹ̀kọ ìkejìdínlógún nínú ìwé òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.” *

Ẹgbẹ́ WGAD tún sọ pé kì í ṣe Ọ̀gbẹni Akhmedov nìkan ni ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan hu irú ìwà àìdáa yìí sí, àmọ́ wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn míì náà tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí ẹ̀sìn wọn. Òótọ́ sì ni ọ̀rọ̀ yìí, torí pé lọ́jọ́ kan náà tí wọ́n mú Ọ̀gbẹni Akhmedov, àwọn ọlọ́pàá tún wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìpàdé, wọ́n sì fipá kó àwọn ìwé ẹ̀sìn wọn.

“Ẹgbẹ́ WGAD mọ̀ dáadáa pé Ọ̀gbẹni Akhmedov kò rú òfin kankan, àmọ́ ó kàn ń lo òmìnira tàbí ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù ú, bó ṣe wa nínú àpilẹ̀kọ ìkejìdínlógún nínú ìwé òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.”—Opinion, ìpínrọ̀ 39.

Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan Gbọ́dọ̀ Wá Nǹkan Ṣe sí Ọ̀rọ̀ Yìí

Ẹgbẹ́ WGAD sọ pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan “tètè wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹni Akhmedov.” Ẹgbẹ́ náà sọ pé ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe ni pé “kí wọ́n dá Ọ̀gbẹni Akhmedov sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí wọ́n san owó ìtanràn fún un, kí wọ́n sì fún un láwọn nǹkan míì tó yẹ.” Ẹgbẹ́ náà tún sọ pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ṣe àwọn àtúnṣe kan sáwọn òfin wọn kí wọ́n lè dáàbò bo ẹ̀tọ́ aráàlú, kó má bàa di pé wọ́n ṣe irú ohun tí wọ́n ṣe fún Ọ̀gbẹni Akhmedov sí ẹlòmíì.

Ní October 13, 2017, agbẹjọ́rò fún Ọ̀gbẹni Akhmedov pe ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Ju Lọ ti Kazakhstan, ó ní kí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí ohun tí ẹgbẹ́ WGAD sọ láìjáfara, kí wọ́n jẹ́ kó mọ̀ pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, kí wọ́n sì jẹ́ kó máa lọ sílé rẹ̀ láyọ̀ àti àlàáfíà.

Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé dùn gan-an pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kárí ayé ló gbà pé ohun tí wọ́n ṣe fún Teymur Akhmedov kò bófin mu rárá àti pé ńṣe ni ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ó yẹ kí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan túbọ fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ tí kálukú ní lábẹ́ òfin láti máa ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú. A retí pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ṣe ohun tí ẹ̀gbẹ́ WGAD sọ láìjáfara, kí wọ́n sì jẹ́ kí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov máa lọ sílé rẹ̀ láyọ̀ àti àlàáfíà.

^ ìpínrọ̀ 2 UN Human Rights Council, Opinions adopted by the Working Group on Arbitrary Detention at its 79th session: No. 62/2017, Kazakhstan, U.N. Doc. A/HRC/WGAD/2017/62 (August 25, 2017).

^ ìpínrọ̀ 6 The International Covenant on Civil and Political Rights