Ní June 20, 2017, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Astana fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Teymur Akhmedov pè lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án. Èyí túmọ̀ sí pé ó máa fi ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún gbára lóòótọ́, wọ́n sì máa fòfin dè é fún ọdún mẹ́ta kó má bàa jọ́sìn. Ẹnì kan tó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn karí ayé wà nílé ẹjọ́ ní June 20 yẹn, ó ní: “Ìrẹ́jẹ gbáà ni, torí ẹ̀rí pọ̀ rẹpẹtẹ láti fi hàn pé Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ò jẹ̀bi.” Àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ ti ń ronú àtipe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn míì.

January 2017 ni àwọn òṣìṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ààbò lórílẹ̀-èdè náà mú Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov, tí wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu. Àtìmọ́lé ló wà títí di May 2, 2017 tí wọ́n fi gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Saryarkinskiy, tí ilé ẹjọ́ sì sọ pé ó jẹ̀bi. Wọ́n ló ń mú kí àwọn èèyàn máa kórìíra ẹ̀sìn míì, ìyẹn sì ta ko Àpilẹ̀kọ 174 (2) nínú Òfin tí ìjọba Kazakhstan ṣe lórí Ìwà Ọ̀daràn. Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov fi gbogbo ẹnu sọ pé òun ò jẹ̀bi, ó ní ṣe lòun kàn ń sọ ohun tí òun gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì, tí òun sì ń fi han àwọn aládùúgbò òun pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó ṣe tán, Òfin Orílẹ̀-èdè Kazakhstan àtàwọn ìwé àdéhùn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ti tọwọ́ bọ̀ lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ fọwọ́ sí i pé èèyàn lè sọ ohun tó bá gbà gbọ́ fáwọn míì.