Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

FEBRUARY 9, 2017
KAZAKHSTAN

Ilé Ẹjọ́ Sọ Pé Kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan Ṣì Wà Látìmọ́lé ní Kazakhstan

Ilé Ẹjọ́ Sọ Pé Kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan Ṣì Wà Látìmọ́lé ní Kazakhstan

Ní January 30, 2017, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Astana fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Teymur Akhmedov pè kí wọ́n lè dá a sílẹ̀ látìmọ́lé tí wọ́n fi sí kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. January 18 ni àwọn aláṣẹ mú un, torí pé wọ́n ń bá àwọn ọkùnrin kan sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe làwọn ọkùnrin ọ̀hún ń díbọ́n bíi pé àwọn máa ń fẹ́ gbọ́rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n fẹ̀sùn kan Teymur pé wọ́n ń “dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn”, wọ́n sì ń “gbé [ẹ̀sìn] kan ga ju àwọn yòókù lọ.” Ilé ẹjọ́ ò jẹ́ ká rí ẹ̀rí kankan tó fi yẹ kí wọ́n ti Teymur mọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn.

Ohun tí ilé ẹjọ́ sọ labẹ gé báyìí, Teymur ò lè pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn mọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Àfi kó wà látìmọ́lé títí wọ́n á fi parí ìwádìí tí wọ́n ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n á sì gbọ́ ẹjọ́ wọn. Tí wọ́n bá sọ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án, tí ilé ẹjọ́ náà sì dá a lẹ́bi, wọ́n lè rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá.