Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

MAY 3, 2017
KAZAKHSTAN

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Kazakhstan Fi Òmìnira Ẹ̀sìn Du Teymur Akhmedov, Wọ́n sì Dá A Lẹ́bi

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Kazakhstan Fi Òmìnira Ẹ̀sìn Du Teymur Akhmedov, Wọ́n sì Dá A Lẹ́bi

Ní May 2, 2017, ilé ẹjọ́ kan nílùú Astana rán Teymur Akhmedov lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún torí pé ó ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn míì. Látìgbà tí orílẹ̀-èdè Kazakhstan ti gbòmìnira lọ́dún 1991, òun ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n máa kọ́kọ́ dá lẹ́bi pé ó jẹ́ ọ̀daràn torí pé ó ń ṣe ẹ̀sìn rẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ti kọ́kọ́ wà látìmọ́lé fún oṣù mẹ́ta kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn dá sí i láti orílẹ̀-èdè míì pé kí wọ́n dá a sílẹ̀, kó máa lọ sílé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ní kò gbọ́dọ̀ jáde nílé, àmọ́ àwọn aláṣẹ ò gbà. Ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta [61] ni, ó ti gbéyàwó, ó sì ti bímọ ọkùnrin mẹ́ta. Ìlera rẹ̀ ò sì dáa rárá.

Wọ́n Fìyà Jẹ Ẹ́ Torí Pé Ó Ń Lo Òmìnira Ẹ̀sìn Tó Ní

January 2017 ni Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ti wà lẹ́nu ọ̀rọ̀ yìí. Ìgbà yẹn làwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ láti Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ààbò lórílẹ̀-èdè Kazakhstan mú un, wọ́n sọ pé ó ṣohun tó ta ko Àpilẹ̀kọ 174(2) nínú Òfin tí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ṣe lórí ìwà ọ̀daràn. Ìgbìmọ̀ náà fẹ̀sùn kàn án pé ó ń “mú kí àwọn èèyàn . . . kórìíra àwọn ẹ̀sìn míì” torí pé ó ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn míì nínú ilé.

Talgat Syrlybayev tó jẹ́ adájọ́ sọ pé ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sọ “dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn,” ó sì ń mú kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fojú kéré ẹ̀sìn kan tàbí kí wọ́n máa gbé ẹ̀sìn wọn ga ju àwọn míì lọ. Adájọ́ tún fòfin de Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov fún ọdún mẹ́ta, pé kò ní lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn rẹ̀. Ká kúkú sọ pé wọ́n ní kò gbọ́dọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run.

Philip Brumley tó jẹ́ Agbẹjọ́rò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Àwọn aláṣẹ ń ṣi òfin lò gan-an. Lọ́dún 2016, àwọn ọkùnrin kan ní kí Teymur wá sínú ilé kan, kó wá bá àwọn sọ ohun tó gbà gbọ́. Wọ́n tiẹ̀ tún wá sílé tiẹ̀ náà. Teymur ò mọ̀ pé wọ́n ń fi kámẹ́rà ká gbogbo ọ̀rọ̀ òun sílẹ̀, tí wọ́n á sì wá fi fẹ̀sùn ọ̀daràn kan òun tó bá yá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé kò sóhun táwọn aláṣẹ ò lè ṣe láti fẹ̀sùn kan àwọn tó ń jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀, kí wọ́n sì ká wọn lọ́wọ́ kò. Ìwà ìrẹ́jẹ gbáà ni!”

Bákan náà, ọ̀rọ̀ ìlera Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ń ká àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lára gan-an. Àrùn kan tó le gan-an ń ṣe é (ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àrùn jẹjẹrẹ), àwọn kan sì ti rọ àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n jẹ́ kó máa lọ sílé, tí wọ́n bá tiẹ̀ máa sọ pé kò gbọ́dọ̀ jáde nílé, àmọ́ àwọn aláṣẹ ò gbà, wọn ò sì bójú tó o bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó nílò ìtọ́jú pàjáwìrì. Àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sọ́dọ̀ Àwùjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìtinimọ́lé Láìnídìí lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn UN Working Group on Arbitrary Detention àtàwọn aṣojú pàtàkì fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn, ohun téèyàn gbà gbọ́ àti òmìnira láti kóra jọ ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì.

Ṣé Òmìnira Ẹ̀sìn Ṣì Máa Gbérí ní Kazakhstan?

Oríṣiríṣi ìṣòro làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Kazakhstan ti kojú lórí bí wọ́n ṣe ń ṣe ẹ̀sìn wọn. Àmọ́ ọwọ́ táwọn aláṣẹ tún gbé lọ́tẹ̀ yìí yàtọ̀, ó sì dáyà jáni, pàápàá bí wọ́n ṣe fi Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sẹ́wọ̀n láìtọ́. Àwọn aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń rọ àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan pé kí wọ́n má gbàgbé pé ìjọba orílẹ̀-èdè náà ti tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ pé àwọn máa jẹ́ káwọn aráàlú lómìnira láti jọ́sìn fàlàlà láìsí pé àwọn aláṣẹ ń yọ wọ́n lẹ́nu.