Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

KAZAKHSTAN

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Ní May 2, 2017, adájọ́ tó ń jẹ́ Talgat Syrlybayev rán Teymur Akhmedov lọ sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó ń “dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn,” ó sì ń “gbé àwọn kan ga ju àwọn yòókù lọ torí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe.” Yàtọ̀ sí pé Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov máa ṣẹ̀wọ̀n, adájọ́ tún sọ pé ilé ẹjọ́ fòfin dè é pé kò gbọ́dọ̀ ṣe ẹ̀sìn rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ní June 20, 2017, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Astana fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov pè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ wà pé kò mọwọ́ mẹsẹ̀.

Wọ́n Fẹ̀sùn Ọ̀daràn Kàn Án Láìnídìí

Ohun tó mú kí wọ́n fẹ̀sùn èké kan Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov lohun kan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2016. Àwọn ọkùnrin kan láwọn nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àṣé wọ́n ń díbọ́n ni. Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tiẹ̀. Ìrọwọ́rọsẹ̀ ni wọ́n fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí fún oṣù méje, ó sì ń fi Bíbélì ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ lórí kókó kọ̀ọ̀kan. Òun ò mọ̀ pé wọ́n ń fi kámẹ́rà ká gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ yìí sílẹ̀, ìyẹn ni wọ́n wá fi fẹ̀sùn kàn án pé ó ti ṣe ohun tó ta ko Àpilẹ̀kọ 174(2) nínú Òfin tí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ṣe tó dá lórí ìwà ọ̀daràn. Òfin yẹn sọ pé ó lòdì láti “mú kí ẹnì kan kórìíra ẹ̀sìn míì,” èyí tó lè “nípa lórí ojú táwọn aráàlú fi ń wo ẹ̀sìn kan,” tó sì lè mú kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fojú kéré ẹ̀sìn kan tàbí kí wọ́n máa gbé ẹ̀sìn wọn ga ju àwọn míì lọ.”

Àmọ́ Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ṣì dúró lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé òun ò rúfin. Òfin fọwọ́ sí i pé ó lè sọ ohun tó gbà gbọ́, bó ṣe wà nínú Àpilẹ̀kọ 18 àti 19 nínú ìwé àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights (ICCPR), èyí tó fọwọ́ sí i pé èèyàn ní “òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn,” èèyàn sì ní “òmìnira láti sọ̀rọ̀.”

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ló ń rí sí i pé ìjọba orílẹ̀-èdè kankan ò ṣohun tó ta ko àdéhùn ICCPR. Ṣáájú àkókò yìí, Ìgbìmọ̀ náà ti sọ fún ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan pé wọ́n ń ṣi òfin tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 174 lò láti “fẹ̀sùn ọ̀daràn kan” àwọn tó ń lo òmìnira ẹ̀sìn tí wọ́n ní àti òmìnira láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́. Ní August 9, 2016, Ìgbìmọ̀ náà kọ̀wé sí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan pé kí wọ́n “jẹ́ kí àwọn aráàlú lómìnira ẹ̀sìn, kí wọ́n lómìnira láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́, kí wọ́n sì lómìnira láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì.” Wọ́n tún sọ pé, “Kí ìjọba rí i pé wọ́n ṣàtúnṣe sí ohun tó wà ní àpilẹ̀kọ 22 nínú Òfin ilẹ̀ wọn, kó lè bá ohun tó wà nínú àdéhùn ICCPR mu, kí wọ́n sì tún rí i pé wọ́n tún gbogbo òfin míì tó ṣe pàtàkì ṣe, kí wọ́n má bàa fòfin de ẹnikẹ́ni lọ́nà tí kò tọ́, torí ohun tó wà ní àpilẹ̀kọ 18 nínú àdéhùn ICCPR ò le tó bí wọ́n ṣe mú ọ̀rọ̀ náà.”

Lọ́dún 2014, Ọ̀gbẹ́ni Heiner Bielefeldt, tó jẹ́ aṣojú pàtàkì tẹ́lẹ̀ fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn àti ohun téèyàn gbà gbọ́, sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan ṣe ń ṣi òfin lò láti fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn èèyàn. Ó sọ pé á dáa tí ìjọba bá jẹ́ kó ṣe kedere pé ohun báyìí-báyìí lẹnì kan máa ṣe ká tó lè sọ pé ó ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn àbí pé agbawèrèmẹ́sìn ni. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun tó wà nínú òfin máa ta ko “òmìnira ẹ̀sìn” táwọn èèyàn ní àti “òmìnira tí wọ́n ní láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́.”

Wọ́n Fi Ọ̀gbẹ́ni Teymur Akhmedov Sẹ́wọ̀n Láìtọ́

Ní January 20, 2017, Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Saryarka No. 2 nílùú Astana fi Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sí àtìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà lù ú torí wọ́n fẹ́ fipá mú un kó lè fẹnu ara ẹ̀ sọ pé òun jẹ̀bi. Bẹ́ẹ̀ sì rè é, Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta [61] yìí yẹ kó lọ gbàtọ́jú torí ó ní àrùn kan tó le (tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àrùn jẹjẹrẹ). Àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sọ́dọ̀ Àwùjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìtinimọ́lé Láìnídìí lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn UN Working Group on Arbitrary Detention àtàwọn aṣojú pàtàkì fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn, ohun téèyàn gbà gbọ́ àti òmìnira láti kóra jọ ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Pẹ̀lú bí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Astana ṣe fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov pè ní June 20, 2017, àwọn agbẹjórò rẹ̀ ń ronú àtipe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn míì.

Ní October 2, 2017, àjọ WGAD tẹ ìpinnu wọn jáde pé ṣe ni ìjọba Kazakhstan fi Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sátìmọ́lé láìtọ́, àti pé ó yẹ kí wọ́n tú u sílẹ̀ ní kíá. Àjọ WGAD rí i pé bí Akhmedov ṣe ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fún àwọn míì “kò dí àlááfíà ìlú lọ́wọ́, ó sì wà lára ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣe ẹ̀sìn rẹ̀” àti pé bí ìjọba ṣe ń fìyà jẹ ẹ́ yìí fi hàn pé ṣe ni wọ́n ń ṣe ẹ̀tanú ẹ̀sìn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ tí àjọ WGAD tẹ ìpinnu wọn jáde, agbẹjóro Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kazakhstan, ó ní kí wọ́n tẹ̀ lé ìpinnu tí àjọ WGAD ṣe, kí wọ́n sì kéde pé Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ò jẹ̀bí, àti pé kí wọ́n dá a sílẹ̀ ní kíá. Àmọ́ ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe ní December 4, 2017 fí hàn pé wọn ò gbá ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà wọlé. Èyí fi hàn pé ìpinnu tí wọ́n ti ṣe ní May 2, 2017 labẹ́ gé.

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

 1. October 2, 2017

  Àjọ WGAD tẹ ìpinnu wọn jáde pé ṣe ni ìjọba Kazakhstan fi Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sátìmọ́lé láìtọ́, àti pé ó yẹ kí wọ́n tú u sílẹ̀ ní kíá

 2. June 20, 2017

  Ilé ẹjọ́ ìlú Astana fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

 3. May 2, 2017

  Ilé ẹjọ́ dá a lẹ́bi, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún.

 4. March 13, 2017

  Ọ̀rọ̀ dé ilé ẹjọ́.

 5. March 1, 2017

  Ilé ẹjọ́ ò gba ohun tí wọ́n sọ.

 6. February 20, 2017

  Àwọn agbẹjọ́rò sọ fún ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n fagi lé ẹjọ́ náà.

 7. January 30, 2017

  Ilé Ẹjọ́ Ìlú Astana fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov pè.

 8. January 18, 2017

  Wọ́n mú Teymur Akhmedov, wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé fún oṣù méjì kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀.