Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ÍŃDÍÀ

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Íńdíà

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Íńdíà

Àtọdún 1905 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lórílẹ̀-èdè Íńdíà. Wọ́n ṣí ọ́fíìsì kan sílùú Bombay (tí wọ́n ń pè ní Mumbai báyìí) lọ́dún 1926, wọ́n sì forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1978. Òfin orílẹ̀-èdè Íńdíà fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ohun kan gbọ́, kó máa ṣe ohun tó gbà gbọ́, kó sì máa sọ ọ́ fáwọn míì, òfin yìí sì ń ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí láǹfààní. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Íńdíà dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre nínú ẹjọ́ Bijoe Emmanuel v. State of Kerala, ọ̀kan pàtàkì ni ẹjọ́ yìí sì jẹ́ torí ó ti túbọ̀ mú kí gbogbo aráàlú lómìnira lábẹ́ òfin. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣe ẹ̀sìn wọn ní Íńdíà láìsí ìdíwọ́. Àmọ́ láwọn ìlú kan, àwọn jàǹdùkú máa ń ṣe wọ́n léṣe, wọ́n sì máa ń dí wọn lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì lẹ́nu ìjọsìn wọn.

Lọ́dún 1977, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fìyàtọ̀ sáàárín kéèyàn máa sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì àti kéèyàn máa yí ẹlòmíì lẹ́sìn pa. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé kò sẹ́ni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti yí ẹlòmíì lẹ́sìn pa dà, àti pé àwọn fọwọ́ sí òfin táwọn ìlú kan ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí. Táwọn jàǹdùkú bá wá ń yọ àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́nu, táwọn ọlọ́pàá sì dá sí i, ohun tí ilé ẹjọ́ sọ ni àwọn jàǹdùkú yẹn sábà máa ń tọ́ka sí, wọ́n á sì parọ́ pé àwọn rí i táwọn Ẹlẹ́rìí ń yí àwọn èèyàn lẹ́sìn pa dà. Láwọn ìlú tí wọn ò ti ṣòfin tó ta ko kéèyàn máa yí ẹlòmíì lẹ́sìn pa dà, ṣe làwọn alátakò máa ń fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀, òfin kan tó ti wà kí orílẹ̀-èdè náà tó gbòmìnira ni wọ́n ń lọ́ po. Èyí ti mú kí àwọn jàǹdùkú máa yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu gan-an, ó sì ti lé ní àádọ́jọ [150] ìgbà tírú ẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀ látọdún 2002. Àwọn aláṣẹ ìlú tún máa ń dá kún ọ̀rọ̀ náà torí pé wọn kì í dáàbò bo àwọn tí wọ́n ń ṣèkà sí bó ṣe yẹ, wọn kì í sì í pe àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ibi yìí lẹ́jọ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Íńdíà ṣì ń lọ bá àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì ń kọ̀wé sí ilé ẹjọ́ kí wọ́n lè gbèjà wọn pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn wọn fàlàlà. Àwọn Ẹlẹ́rìí ń retí pé kí àwọn aláṣẹ ìlú àtàwọn aráàlú máa tẹ̀ lé ohun tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sọ nínú ẹjọ́ Bijoe, pé: “Àṣà ilẹ̀ wa kò fi kọ́ wa pé ká máa ṣe ẹ̀tanú; ohun tá à ń kọ́ àwọn èèyàn ni pé ẹ̀tanú ò dáa; òfin ilẹ̀ wa náà sọ pé ká má ṣe ẹ̀tanú; ẹ máà jẹ́ ká bomi là á.” Àwọn Ẹlẹ́rìí ń retí pé ìsapá àwọn máa jẹ́ káwọn jàǹdùkú tó ń yọ wọ́n lẹ́nu jáwọ́, kí wọ́n lè lómìnira ẹ̀sìn láwùjọ.