Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù nítòsí afárá Bridge of Peace, nílùú Tbilisi

FEBRUARY 21, 2017
GEORGIA

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Fọwọ́ sí I Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Ṣe Ẹ̀sìn Wọn ní Jọ́jíà

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Fọwọ́ sí I Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Ṣe Ẹ̀sìn Wọn ní Jọ́jíà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà ń gbádùn òmìnira ẹ̀sìn lónìí, àmọ́ bó ṣe rí lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn kọ́ nìyẹn. Ìjọba ti forúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí sílẹ̀ lábẹ́ òfin báyìí, wọ́n sì ti jẹ́ kí wọ́n máa jọ́sìn fàlàlà. Àmọ́ ṣáájú àkókò yìí, lọ́dún 1999 sí 2003, nǹkan ò rí báyìí rárá. Ṣe ni ìjọba gba àwọn agbawèrèmẹ́sìn láyè nígbà yẹn kí wọ́n gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọn ò mú un ní kékeré rárá, ìjọba sì kọ̀ láti pe àwọn jàǹdùkú yẹn lẹ́jọ́.

Inúnibíni tó le tí wọ́n ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn mú kí wọ́n kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn ECHR) láìmọye ìgbà. Ọ̀kan lára ìwé tí wọ́n kọ, tó dá lórí ẹjọ́ Case of Tsartsidze and Others v. Jọ́jíà, ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta tó wáyé lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà lọ́dún 2000 àti 2001. Lásìkò yẹn, àwọn jàǹdùkú hùwà ipá sáwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n da ìpàdé wọn rú, wọ́n ba ohun ìní wọn jẹ́, àwọn ọlọ́pàá lù wọ́n nílùkulù, wọ́n tún sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn.

Ní January 17, 2017, ilé ẹjọ́ ECHR sọ ìpinnu wọn lórí ẹjọ́ Tsartsidze, wọ́n sì rí i pé àwọn aláṣẹ ti tẹ ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú. Ilé ẹjọ́ náà rí i pé àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Jọ́jíà jẹ̀bi, nínú kó jẹ́ pé wọ́n lọ́wọ́ sí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, tàbí kó jẹ́ pé wọn ò gbèjà àwọn tọ́rọ̀ kàn. Ilé ẹjọ́ tún rí i pé àwọn ilé ẹjọ́ àtàwọn adájọ́ lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà ò ṣe nǹkan kan sí ìwàkiwà táwọn èèyàn hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí pé àwọn náà ń gbè sẹ́yìn àwọn yẹn, wọn ò sì ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà tó bó ṣe yẹ.

Ìgbà Kẹta tí Ilé Ẹjọ́ Máa Dá Ìjọba Lẹ́bi Torí Inúnibíni tí Wọ́n Ń Kọ́wọ́ Tì

Ìgbà kẹta nìyí tí ilé ẹjọ́ ECHR máa dá ìjọba orílẹ̀-èdè Jọ́jíà lẹ́bi. Ilé Ẹjọ́ náà sọ pé láàárín ọdún 1999 sí 2003, ṣe ni wọ́n ń “hùwà ipá sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri orílẹ̀-èdè náà torí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.” Nínú ẹjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ilé ẹjọ́ ECHR dá, wọ́n rí i pé ìjọba orílẹ̀-èdè Jọ́jíà ò tẹ̀ lé àdéhùn European Convention on Human Rights, torí pé wọn ò jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira ẹ̀sìn, wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tanú sí wọn.

Bí Ilé Ẹjọ́ náà ṣe ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Jọ́jíà nígbà yẹn nìyí: “Bákan méjì ni, nínú kó jẹ́ pé àwọn tó jẹ́ agbódegbà fáwọn aláṣẹ ní Jọ́jíà lọ́wọ́ sí ìwà ipá táwọn èèyàn hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tàbí kó jẹ́ pé wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn kan tó hùwàkiwà yìí, tí wọ́n wá ń ṣe bàbá ìsàlẹ̀ fún wọn. Àwọn aláṣẹ ò sì fìyà ohun tí wọ́n ṣe jẹ wọ́n, torí ẹ̀ làwọn míì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri orílẹ̀-èdè náà.”

Ilé Ẹjọ́ ECHR Tẹ̀ Lé Òfin, Wọ́n sì Jẹ́ Kí Wọ́n Lómìnira Ẹ̀sìn

Nínú ẹjọ́ Tsartsidze, ilé ẹjọ́ ECHR rí i pé ní ìgbà mẹ́ta táwọn èèyàn gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tí ò bófin mu táwọn ọlọ́pàá ṣe ló kóyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí yìí.

  • Ní September 2, 2000, nílùú Kutaisi, àwọn ọlọ́pàá mú Ọ̀gbẹ́ni Dzamukov lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Wọ́n gba àwọn ìwé ẹ̀sìn tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n hùwà àìdáa sí i, wọ́n sì lù ú. Lọ́jọ́ kejì, ọlọ́pàá kan lọ bá Ọ̀gbẹ́ni Gabunia, ó fún un lẹ́ṣẹ̀ẹ́ níkùn, ó sì fa àwọn ìwé ẹ̀sìn tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ ya.

  • Ní October 26, 2000, nílùú Marneuli, àwọn ọlọ́pàá ya wọ ibì kan táwọn Ẹlẹ́rìí ti ń ṣèpàdé, wọ́n sì gba àwọn ìwé ẹ̀sìn wọn. Wọ́n mú Ọ̀gbẹ́ni Mikirtumov, tó ń ṣe ìwàásù lọ́wọ́ nípàdé yẹn, wọ́n sì mú Ọ̀gbẹ́ni Aliev, ẹni tó nilé tí wọ́n ti ń ṣèpàdé, wọ́n wá kó àwọn méjèèjì lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Nígbà tó yá, àwọn ọlọ́pàá fipá mú Ọ̀gbẹ́ni Mikirtumov wọnú mọ́tò kan, wọ́n sì wà á lọ sẹ́yìn ìlú. Wọ́n já a síbẹ̀, wọ́n ní kò gbọ́dọ̀ pa dà wọ̀lú mọ́. Wọ́n tún sọ fún Ọ̀gbẹ́ni Aliev pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe ìpàdé Ajẹ́rìí nínú ilé rẹ̀ mọ́.

  • Ní March 27, 2001, nílùú Rustavi, àwọn jàǹdùkú ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan tí wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ya wọ inú ilé Ọ̀gbẹ́ni Gogelashvili nígbà táwọn èèyàn ń ṣèjọsìn lọ́wọ́ níbẹ̀. Wọ́n hùwà àìdáa sáwọn tó wà níbẹ̀, wọ́n sì fipá lé wọn jáde nínú ilé náà. Àwọn jàǹdùkú náà gba àwọn ìwé ẹ̀sìn wọn, nígbà tó sì di ọjọ́ kejì, wọ́n dáná sun ún ní gbangba, níbi ọjà kan tó wà nítòsí. Pẹ̀lú gbogbo èyí, àwọn ọlọ́pàá ò dá sí i, wọn ò dáàbò bo àwọn èèyàn yìí.

Lórí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta tó wáyé ní Jọ́jíà yìí, àwọn tọ́rọ̀ kàn gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́, àmọ́ ilé ẹjọ́ ò rí nǹkan ṣe sí i. Bí ilé ẹjọ́ ECHR ṣe sọ, ṣe làwọn adájọ́ ní Jọ́jíà ń gbè sẹ́yìn àwọn ọlọ́pàá, wọn ò sì fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí táwọn tọ́rọ̀ kàn mú wá sílé ẹjọ́. Ilé ẹjọ́ ECHR sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn adájọ́ ní Jọ́jíà ṣe lórí àwọn ẹjọ́ táwọn èèyàn gbé wá yìí, ó ní:

Pẹ̀lú bí àwọn ilé ẹjọ́ ò ṣe túṣu àwọn ẹjọ́ yìí dé ìsàlẹ̀ ìkòkò, tí wọ́n kọ̀ láti yẹ àwọn agbófinró lọ́wọ́ wò, tí wọn ò sì fara balẹ̀ gbọ́ tẹnu àwọn tó gbé ẹjọ́ wá, láìsí ẹ̀rí gidi kan tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kò sí tàbí ṣùgbọ́n, ilé ẹjọ́ ECHR gbà pé ṣe ni àwọn adájọ́ ń lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn tó ń hùwà ipá sáwọn èèyàn yìí.

Torí pé ilé ẹjọ́ ECHR rí i pé ìjọba ti fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn yìí dù wọ́n, èyí tó ta ko Àpilẹ̀kọ 9 (ìyẹn, òmìnira ẹ̀sìn) àti 14 (ìyẹn, ẹ̀tanú) nínú àdéhùn European Convention on Human Rights, wọ́n ní kí ìjọba sanwó gbà-máà-bínú fún wọn. Àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti ogójì [11,840] owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlélọ́gọ́ta [10,762] owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, tí wọ́n ná sórí ẹjọ́.

Ṣé Ìdájọ́ Yìí Máa Nípa Lórí Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti Azerbaijan?

Nígbà tí ilé ẹjọ́ ECHR ń parí ẹjọ́ tí wọ́n ń dá lọ, wọ́n tún àwọn ìpinnu tí wọ́n ti ṣe lórí àwọn ẹjọ́ kan tẹ́lẹ̀ sọ, bíi ẹjọ́ Gldani àti Begheluri ní orílẹ̀-èdè Jọ́jíà àti ẹjọ́ Kuznetsov àti Krupko ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ìjọba orílẹ̀-èdè Jọ́jíà ti ń ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ECHR ṣe lórí àwọn ẹjọ́ tí wọ́n ti dá sẹ́yìn, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jọ́jíà sì ń dùn pé òfin ń dáàbò bo àwọn dáadáa báyìí, èyí sì ti jẹ́ kí wọ́n lè máa pàdé pọ̀, kí wọ́n sì lómìnira láti máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ láìséwu.

André Carbonneau, ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kárí ayé tó wà níbi àwọn ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ gbọ́ ní Jọ́jíà, tó sì wà lára àwọn tó kọ̀wé sí ilé ẹjọ́ ECHR, sọ pé: “Ìpinnu amóríyá tí ilé ẹjọ́ ECHR ṣe yìí ti jẹ́ kó ṣe kedere pé ilé ẹjọ́ náà ò ní fàyè gba ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ rẹ̀ kí wọ́n máa fi òmìnira ẹ̀sìn táwọn aráàlú ní dù wọ́n. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn pé ìjọba orílẹ̀-èdè Jọ́jíà ń tẹ̀ lé àwọn ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ECHR ṣe kí àwọn Ẹlẹ́rìí lè lómìnira ẹ̀sìn. À ń retí pé káwọn orílẹ̀-èdè míì tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù, bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, fi èyí sọ́kàn.”

Ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR dá lẹ́nu àìpẹ́ yìí jẹ́ káwọn aráàlú lè pàdé pọ̀ láti jọ́sìn fàlàlà, kí wọ́n sì bá àwọn aládùúgbò wọn sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ láìsí wàhálà. Àwọn aráàlú mọyì òmìnira tí wọ́n ní yìí gan-an. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń retí pé kí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR dá yìí nípa rere lórí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti Azerbaijan, torí irú àwọn ẹjọ́ yìí kan náà ṣì wà nílé ẹjọ́ níbẹ̀.