Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

FRANCE

Àlàyé Ṣókí Nípa Ilẹ̀ Faransé

Àlàyé Ṣókí Nípa Ilẹ̀ Faransé

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílẹ̀ Faransé lọ́dún 1906, wọ́n sì ti lómìnira láti máa ṣe ẹ̀sìn wọn. Àmọ́ ní nǹkan bí ọdún 1995, ìròyìn kan tẹ àwọn aṣòfin lọ́wọ́ pé ẹ̀sìn tó dalẹ̀ ẹgbẹ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Faransé, wọ́n sì fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí pé èèyàn tó léwu láwùjọ ni wọ́n. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn náà ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ lábẹ́ òfin, wọ́n ti fi dájú sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí ti wá mú kí wọ́n sọ wọ́n lórúkọ tí ò dáa láwùjọ, kí wọ́n sì máa ṣe ẹ̀tanú sí wọn.

Èyí tó wá burú jù tí ìjọba ṣe, tó sì hàn sójútáyé ni pé wọ́n bu owó orí gọbọi lé ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà torí àwọn ọrẹ tí ọ́fíìsì náà ń rí gbà, lérò àtisọ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà di ẹdun arinlẹ̀. Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìndínlógún [16] tí wọ́n ti jọ ń fa ọ̀rọ̀ yìí, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn ilé ẹjọ́ ECHR) fẹnu kò lórí ẹjọ́ náà ní June 30, 2011, wọ́n sì sọ pé ìjọba ilẹ̀ Faransé ti fi ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀sìn du àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ẹjọ́ míì wà tó jẹ mọ́ ẹ̀tanú tí ilé ẹjọ́ ti dá àwọn Ẹlẹ́rìí láre nílẹ̀ Faransé. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ìgbà tí àwọn aláṣẹ ò fún wọn níwèé àṣẹ láti kọ́lé, tí wọ́n kọ̀ láti fún wọn níwèé ẹ̀rí tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun kan gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láwọn ìgbà táwọn kan kọ̀ láti yá wọn ní gbọ̀ngàn tí wọ́n fẹ́ lò fún ìjọsìn nílùú wọn.

Bí ìjọba ilẹ̀ Faransé ṣe sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ burúkú yìí ti mú káwọn èèyàn má fọkàn tán wọn mọ́ láwùjọ, láìka bí ilé ẹjọ́ ECHR ṣe dá wọn láre àti báwọn ilé ẹjọ́ míì lóríṣiríṣi nílẹ̀ Faransé ṣe dá wọn láre. Torí náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn jàǹdùkú ṣì máa ń lu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ń yọ wọ́n lẹ́nu, tí wọ́n sì ń ba àwọn ilé ìjọsìn wọn jẹ́.