Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ọ̀RÀN ÒFIN

Egypt

JUNE 7, 2017

‘Mò Ń Retí Ìgbà tí Wọn Ò Ní Fòfin Dè Wá Láìtọ́ Mọ́’

Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira ẹ̀sìn ní Íjíbítì. Bí àpilẹ̀kọ kan tí iléeṣẹ́ ìròyìn gbé jáde lórí ìkànnì ṣe sọ, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Íjíbítì ń bá a lọ láti fi hàn pé èèyàn dáadáa làwọn bíi ti àtẹ̀yìnwá, láìka ohun tójú wọn ń rí sí.