Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

BỌ̀GÉRÍÀ

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà

Àtọdún 1888 ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà. Lọ́dún 1938, wọ́n forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè náà, àmọ́ nígbà tó di ọdún 1944, tí ìjọba Kọ́múníìsì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso orílẹ̀-èdè náà, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé e. Nǹkan wá nira gan-an fáwọn Ẹlẹ́rìí, ṣe ni wọ́n ń fòfin dè wọ́n títí wọ́n fi pa dà rí orúkọ ẹ̀sìn wọn fi sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1991. Orúkọ tí wọ́n lò ni Christian Association of Jehovah’s Witnesses. Àmọ́ lọ́dún 1994, àwọn èèyàn ní “ṣẹ̀ṣẹ̀ dé” làwọn ẹ̀sìn kan, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n lórúkọ jẹ́ káàkiri. Ni ìjọba náà bá tún ṣòfin lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, bó ṣe di pé wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké míì nìyẹn. Àtìgbà yẹn làwọn ọlọ́pàá ti ń mú àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n ń da ìpàdé wọn rú, tí wọ́n sì ń gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìtẹ̀jáde wọn. Bẹ́ẹ̀, àwọn ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà ò gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí.

Àwọn Ẹlẹ́rìí gbìyànjú títí kí wọ́n lè wá nǹkan ṣe sí i, àmọ́ pàbó ni gbogbo akitiyan wọn lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà já sí. Ni wọ́n bá kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù kí wọ́n bá wọn dá sí i. Lọ́dún 1998, 2001 àti 2004, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn yìí bá àwọn Ẹlẹ́rìí àti ìjọba orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà dá sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì ní kí wọ́n lọ yanjú ẹ̀ ní ìtùnbí-ìnùbí. Lẹ́yìn tí wọ́n sì yanjú ẹ̀, ìjọba pa dà forúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Wọ́n tún fọwọ́ sí i pé wọ́n lómìnira ẹ̀sìn, wọ́n sọ pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti kọṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é, wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú, wọ́n sì lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fàlàlà.

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà dùn pé àwọn lómìnira ẹ̀sìn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì ń ṣe ẹ̀sìn wọn láìsí wàhálà. Àmọ́ àwọn aláṣẹ ìlú kan lórílẹ̀-èdè náà ń ká àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ kò, ṣe ni wọ́n ń ṣi òfin lò láti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wọn, wọn ò sì gbà wọ́n láyè láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará ìlú kan lu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ṣe wọ́n ṣúkaṣùka. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbófinró máa ń dá sí ọ̀rọ̀ náà, wọn kì í pe àwọn alátakò ọ̀hún lẹ́jọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gbèjà àwọn tí wọ́n ń lù. Àwọn Ẹlẹ́rìí ò yé lọ bá àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà lórí ọ̀rọ̀ yìí, kódà, ẹjọ́ kan tó dá lórí ọ̀rọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan táwọn aláṣẹ ò fọwọ́ sí pé káwọn Ẹlẹ́rìí kọ́ ṣì wà ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.