Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JUNE 14, 2016
BỌ̀GÉRÍÀ

Àjọ Kan Lábẹ́ Ìjọba Orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà Fìyà Jẹ Àwọn Tó Ń Ṣe Ẹ̀tanú Ẹ̀sìn

Àjọ Kan Lábẹ́ Ìjọba Orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà Fìyà Jẹ Àwọn Tó Ń Ṣe Ẹ̀tanú Ẹ̀sìn

Ìjọba ti dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà láre. Wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn lómìnira ọrọ̀ sísọ, àmọ́ wọn ò gbà kí wọ́n máa fìyẹn ṣe ẹ̀tanú ẹ̀sìn sáwọn míì. Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀tanú lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà kíyè sí i pé iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n SKAT TV ní Bọ̀géríà àtàwọn oníròyìn méjì tó ń bá wọn ṣiṣẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ tan irọ́ kálẹ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń ṣe ohun tó máa mú káwọn èèyàn máa hùwà ipá sáwọn Ẹlẹ́rìí. Ohun tí Àjọ náà parí èrò sí ni pé ohun tí iléeṣẹ́ SKAT TV ṣe “ò ṣeé gbójú fò.”

Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n Ń Mú Káwọn Èèyàn Kórìíra Ẹ̀sìn, Kí Wọ́n sì Máa Hùwà Ipá

Àwọn iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà sábà máa ń ṣe àwọn ètò tó ń ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́, pàápàá àwọn oníròyìn iléeṣẹ́ SKAT TV. Ṣe ni wọ́n ń ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́, wọ́n sì ń mú káwọn èèyàn máa rò pé ọ̀daràn paraku làwọn Ẹlẹ́rìí. Kò síbi táwọn èèyàn kì í ti wo àwọn ètò yìí ní gbogbo orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà, wọ́n sì ti gbé e sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Ohun táwọn èèyàn ń wò nínú àwọn ètò yìí tún ti mú kí wọ́n kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n sì máa hùwà ipá sí wọn. Nínú ètò kan tí wọ́n ṣe ní May 2011, iléeṣẹ́ SKAT TV sọ pé àwọn tó lọ ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba (ìyẹn ilé ìjọsìn) wọn nílùú Burgas, tí wọ́n sì lù wọ́n nílùkulù ò jẹ̀bi. Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé jọ láti ṣe ìrántí ikú Kristi tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún, ni àwọn jàǹdùkú kan bá ya wọ ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì lu ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ nílùkulù. Márùn-ún nínú àwọn tó wà níbẹ̀ ni wọ́n gbé lọ sí ọsibítù torí wọ́n fara pa. Ètò tí iléeṣẹ́ SKAT TV ṣe yẹn mú káwọn èèyàn tún ṣe irú ohun táwọn jàǹdùkú yẹn ṣe, wọ́n tiẹ̀ tún ń sọ ọ́ nínú àwọn ètò míì tí wọ́n wá ń ṣe lẹ́yìn ìyẹn pé ìyà tọ́ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. *

Lẹ́yìn táwọn ètò yẹn gorí afẹ́fẹ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n lu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùkulù, wọ́n sì ba ọ̀pọ̀ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn jẹ́. Àwọn aláṣẹ àwọn àgbègbè kan tiẹ̀ ti ṣòfin tó ká àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ kò lágbègbè wọn.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣèpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba nílùú Burgas

Àjọ Náà Fìyà Jẹ Àwọn Tó Rú Òfin, Tí Wọ́n Tún Ṣe Ohun Tí Ò Bójú Mu

Ní February 2012, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀wé sí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀tanú nípa àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n mẹ́fà tí iléeṣẹ́ SKAT TV gbé gorí afẹ́fẹ́ lọ́dún 2010 àti 2011. Àwọn Ẹlẹ́rìí fẹ̀sùn kan iléeṣẹ́ SKAT TV pé ṣe ni wọ́n ń ṣe ẹ̀tanú àwọn, bí wọ́n sì ṣe ń gbé àwọn ètò yìí kiri ti mú káwọn èèyàn máa yọ àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́nu, kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn, kí wọ́n sì máa ṣe ẹ̀tanú wọn.

Ní January 25, 2016, Àjọ náà fẹnu kò, wọ́n sì sọ pé òótọ́ ni ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ. Wọ́n rí i pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí iléeṣẹ́ SKAT TV àtàwọn oníròyìn wọn méjì fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tí wọ́n sì ń sọ nípa wọn ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Àjọ náà rí i pé ẹ̀tanú ẹ̀sìn ni wọ́n fi àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n mẹ́fà náà ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tí iléeṣẹ́ yẹn sì ṣe ta ko ohun tó yẹ káwọn oníròyìn máa ṣe, èyí tó fi hàn pé wọn ò mọṣẹ́ wọn níṣẹ́.

Ohun tí Àjọ náà sọ nígbà tó ń ṣèdájọ́ ni pé “wọn ò jẹ́ kí àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn yìí rímú mí, torí wọ́n ń hùwà tí ò yẹ, tí ò sì bófin mu sí gbogbo wọn.” Àjọ náà sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òfin fún èèyàn lómìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kò fàyè gba kéèyàn máa sọ̀rọ̀ burúkú nípa àwọn míì. Wọ́n wá sọ pé “ohun tí iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n yẹn ṣe ò ṣeé gbójú fò.”

Ohun tí Àjọ náà parí èrò sí ni pé irọ́ tí wọ́n pa mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ kékeré. Bí iléeṣẹ́ SKAT TV àtàwọn oníròyìn wọn ò ṣe gba ẹ̀bi wọn lẹ́bi, kí wọ́n sì ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe tiẹ̀ tún múnú bí àjọ yìí. Kí wọ́n lè mọ bí ohun tí wọ́n ṣe ṣe wúwo tó, Àjọ náà bu owó ìtanràn lé wọ́n, kódà, owó ọ̀hún ju iye tí wọ́n sábà máa ń bù lé àwọn tó jẹ̀bi.

Ìgbésẹ̀ Tí Ò Jẹ́ Kí Ìyà Jẹ Wọ́n Gbé

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbóríyìn fún Àjọ náà pé wọn ò fàyè gba àwọn oníròyìn tó ń bani lórúkọ jẹ́, tó sì ń ṣe ẹ̀tanú. Ìkìlọ̀ ni ìdájọ́ tí Àjọ náà ṣe tún máa jẹ́ fáwọn iléeṣẹ́ ìròyìn míì tó wà lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà táwọn náà ti ń fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níṣòro pé wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ̀sùn èké kan àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́, wọn ò sì gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ burúkú nípa wọn.

Ọ̀gbẹ́ni Krassimir Velev tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bọ̀géríà sọ pé, “Kò sẹ́ni tó máa fẹ́ kí wọ́n máa tan irọ́ kálẹ̀ nípa òun, àwa náà ò fẹ́ bẹ́ẹ̀. Etí tó ti gbọ́ àlọ sì yẹ kó gbọ́ àbọ̀, ó yẹ kí àwọn ará Bọ̀géríà tó ti gbọ́ ìgbọ́kúgbọ̀ọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbọ́ òkodoro òtítọ́ nípa wa. Inú wa sì dùn pé Àjọ náà ti gbé ìgbésẹ̀ kí ọ̀rọ̀ náà lè yanjú.”

^ ìpínrọ̀ 5 Ní July 8, 2015, iléeṣẹ́ SKAT TV tún gbé fídíò kan sáfẹ́fẹ́, èyí tó dá lórí ìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí ní April 17, 2011. Wọn ò yé ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́, wọ́n sì ń mú káwọn èèyàn máa kórìíra wọn.

 

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ

Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?

Ní ṣókì, wo ohun mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tá a gbà gbọ́.