Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JANUARY 28, 2016
AZERBAIJAN

Wọ́n Ti Pa Dà Tú Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova Sílẹ̀ ní Àtìmọ́lé tí Wọ́n Fi Wọ́n sí Láìtọ́

Wọ́n Ti Pa Dà Tú Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova Sílẹ̀ ní Àtìmọ́lé tí Wọ́n Fi Wọ́n sí Láìtọ́

Lẹ́yìn tí Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova ti lo oṣù mọ́kànlá [11] lẹ́wọ̀n, wọ́n tú wọn sílẹ̀ ní January 28, 2016. Akram Gahramanov tó jẹ́ adájọ́ ti dá wọn lẹ́bi, ó sì bu owó ìtanràn gọbọi lé wọn, ó ní kí wọ́n san owó tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900,000 naira; 7,000 manat, tàbí 3,932 euros) torí pé wọ́n kàn ń pín ìwé pẹlẹbẹ kan tó dá lórí ẹ̀sìn. Ó wá fagi lé owó náà torí àwọn obìnrin náà ti wà lẹ́wọ̀n láti February 17, 2015. Ohun tí adájọ́ yìí ṣe ta ko àṣẹ tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pa pé kí ìjọba Azerbaijan sanwó gbà-máà-bínú fún àwọn obìnrin náà torí wọ́n tì wọ́n mọ́lé láìtọ́.

Ara tu Arábìnrin Zakharchenko àti Arábìnrin Jabrayilova torí wọ́n ti dá wọn sílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì nílò ìtọ́jú gidigidi. Wọ́n ti pa dà sílé báyìí lọ́dọ̀ àwọn ẹbí wọn, ara wọn sì ti ń mókun.