Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

FEBRUARY 10, 2017
AZERBAIJAN

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Azerbaijan Dá Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova Láre

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Azerbaijan Dá Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova Láre

Ní February 8, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Azerbaijan sọ pé Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova ò jẹ̀bi bí wọ́n ṣe ń pín ìwé ẹ̀sìn wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò kọ́kọ́ gbàṣẹ lọ́wọ́ Ìjọba. Hafiz Nasibov, tó jẹ́ adájọ́, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Àwọn Ọ̀daràn ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ kéde pé Ilé Ẹjọ́ ò rí ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn nínú ohun táwọn obìnrin méjì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ṣe, wọ́n sì ti fagi lé ohun táwọn ilé ẹjọ́ tó dá ẹjọ́ náà ṣáájú sọ.

Nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ náà, agbẹjọ́rò Arábìnrin Zakharchenko àti Arábìnrin Jabrayilova sọ pé ìjọba tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn obìnrin yìí lójú, torí bí wọ́n ṣe fìyà jẹ wọ́n láìtọ́. Ilé Ẹjọ́ gba àwọn obìnrin méjèèjì láyè láti sọ ohun tójú wọn rí ní àtìmọ́lé tí wọ́n fi wọ́n sí fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan, kí wọ́n sì sọ bó ṣe rí lára wọn.

Jason Wise, tó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kárí ayé sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Àwọn Ọ̀daràn ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fagi lé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn obìnrin yìí. Irú èyí ò ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí ní Azerbaijan, pé kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fagi lé ohun táwọn ilé ẹjọ́ tó ti kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà sọ. À ń retí pé kí Ilé Ẹjọ́ Baku Sabail tún fọwọ́ sí i pé ó tọ́ kí ìjọba sanwó gbà-máà-bínú fáwọn obìnrin yìí.”